Ẹ ba wa bẹ Buruji Kashamu, ko dẹyin lẹyin ẹgbẹ lebọ- Bọde Simeon - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Tuesday 9 June 2020

Ẹ ba wa bẹ Buruji Kashamu, ko dẹyin lẹyin ẹgbẹ lebọ- Bọde Simeon


 
Lara awọn ọmọ ẹgbẹ lebọ to fehonu han
Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee,ni ẹgbẹ oṣelu Lebọ, tipinlẹ Ogun, fehonu wọn han lori bi wọn ṣe ni  Abayọmi Oluwafẹmi Onigbinde, tọpọ mọ si Arabambi, ṣe n ba wọn loju jẹ, to si n jẹ ki Buruji Kashamu maa lo oun lati fi ba nnkan jẹ patapata.

Bo tilẹ jẹ pe awọn to fehonu naa han ko pọ nitori ti arun koronafairọọsi to wa lode ṣugbọn gbogbo wọn ni wọn lawọn fi mọ sọkan lati sọ faraye pe iṣẹ ti Arabambi jẹ kaakiri, ki i ṣe ẹgbẹ naa lo ran ati pe awọn ti yọ danu gẹgẹ bi alaga ẹgbẹ ọhun.

Ninu ọrọ Ọgbẹni Bọde Simeon, to jẹ igbakeji alaga ẹgbẹ naa lapapọ, ko to di pe wọn gbe iwe iwọde wọn sita lo ti sọ pe ẹnikẹni to ba ba Arabambi dowopọ, ṣe fun ara ẹ ni,nitori ki i ṣe ọmọ ẹgbẹ lebọ,  ati gbogbo nnkan to n ṣe, apo ara ẹ ni.

O ni ọkunrin naa kan n lo orukọ ẹgbẹ lati fi ba awọn lorukọ jẹ ni.
O fi kun ọrọ ẹ pe ‘’ Arabambi ati Buruji Kashamu, nnkan kan naa lawọn mejeeji, ọmọọdọ Buruji ni Arabambi, a o wa fẹ ki Buruji wa ba ẹgbẹ lebọ jẹ, bo ṣe ba PDP jẹ, to si n ba jẹ lọwọlọwọ.

O tun ṣalaye pe awọn mejeeji nnkankan naa ni wọn, ẹyẹ kan ṣoṣo lo ṣu wọn, o ni ibi ti nnkan yoo ti bajẹ, ko ma latunṣe lawọn mejeeji maa n wa.
  

Simeon tun sọ pe ‘’Ẹ ba wa bẹ Buruji Kashamu, ko dẹyin lẹyin ẹgbẹ lebọ, ki i ṣe eyi taa le gbe lee lọwọ, ki i ṣẹgbẹ to le gba, ko le  ba ẹgbẹ naa jẹ, nitori a mọ pe awọn mejeeji ti lẹdi apo pọ, awa rọ gbogbo awọn agbaagba, awọn aṣaaju wa lati  ba wa kilọ fun, ko ma da wahala silẹ ninu ẹgbẹ wa. Lati ori Niyi Ọṣọba, nitori a mọ ọpọ ọrọ ibajẹ ti Buruji ati Arabambi ti ṣe si wọn’’.

Ẹni yii ki i ṣe ẹni abuku, ẹni iyi, ẹni ẹyẹ ni, ẹni apọnle ni, ẹni to jẹ pe abẹ wọn lawa sa si gẹgẹ bi ẹgbẹ lebọ,  gbogbo nnkan ti Arabambi sọ nipa wọn, a ko ran niṣẹ, ki i ṣe ẹgbẹ lebọ lo sọ iru awọn nnkan wonyii’’

Bẹẹ lo ni eyi ti wọn ṣe si Bayọ Dayọ, tawọn mọ gẹgẹ bi alaga PDP nipinlẹ Ogun, gbogbo nnkan ti wọn n ṣe yẹn, ki i ṣe nnkan taye fọwọ si, o wa ni awọn  fẹ kawọn agba oloṣelu yii bi Ọtunba Gbenga Daniel, Aṣofin Ibikunle Amosun, GNI, JMK, Gomina Dapọ Abiọdun, Oloye Oluṣẹgun Ọṣọba, ba awọn ba Kashamu sọrọ, ko jawọ ninu ẹgbẹ oṣelu lebọ.

No comments:

Post a Comment

Pages