Itiju nla nija to kọ ti ko pari ninu ẹgbẹ PDP nipinlẹ Ogun jẹ fun wa-Ṣẹgun Sowumi - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Monday 8 June 2020

Itiju nla nija to kọ ti ko pari ninu ẹgbẹ PDP nipinlẹ Ogun jẹ fun wa-Ṣẹgun Sowumi




Ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ogun ni Ṣẹgun Ṣowumi, o si wa lara awọn to gbe apoti ibo fun aṣoju-ṣofin niluu Abuja, fun agbegbe Abẹokuta South,ọkunrin naa ba oniroyin wa sọrọ nipa wahala to n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ naa ati ọna abayọ, oun to ba wa sọ niyii.

Wahala to n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ oṣelu PDP

Nnkan to ti ni loju gba a ni, nitori tawọn eeyan ba ti ṣe pẹlu ara wọn fọdun mẹwaa, o tẹ ori mi kodo pupọ pe o le ri bẹẹ yẹn,Ṣe mo fẹ sọ pe eyi ti Bayọ Dayọ n bu ara wọn ati Buruji, ṣe mo fẹ sọ pe iwa to dara ni, ti o ba fẹ kuro lọdọ Buruji lọ sọdọ ẹlomii in, ko sẹnikan to le fi okun so ẹnikan mọlẹ, eeyan le kuro ṣugbọn ko gbọdọ ma ranti pe ida to ba ba akọ jẹ, ile ara ẹ lo n ba jẹ.

Ọmọ Ijẹbu Igbo kan naa ni wọn, o niye igba ti wọn fi n ṣe tẹgbọn taburo wọn, o niye igba ti wọn fi jọ ṣe wọlewọde, ti wọn jẹun papọ lori tebu kan naa.O niye ọdun ti wọn forukọ Dayọ Bayọ da ẹgbẹ lapapọ laamu,  to jẹ pe oun ati Kashamu ni wọn jọ wa nibẹ.

Ti mo ba ṣetan lati kuro nibẹ iye ọdun to ba gba ẹ lati bẹ Kashamu tabi ọna, iṣẹ tiẹ niyẹn, nitori Kashamu ti wọn n sọ yẹn. ṣe o ṣe fi silẹ nita ni, nigba ti Bayọ Dayọ kuro nibẹ, to n jẹ ki ibẹ yẹn maa gbona, iṣẹ to gba ti ko ṣe daadaa lo n yọ silẹ yẹn o, igba to si ti pinnu pe kawọn pada sọdọ ẹgbẹ lapapọ yẹn, gbogbo ọgbọn to fi lo ọdun mẹwaa pẹlu Buruji yẹn lo yẹ ko lo debi ti Buruji yoo gba, ki wọn si ṣe bẹẹ, nitori pẹlẹ lakọ labo.

Mi o si ṣetan lati wa ninu ọrọ yẹn, nitori ẹni to ba maa pari ija, o ni lati sọ ọrọ sọ, ko ma baa di wi pe ko ni le bẹ wọn mọ. Ibi ti mo duro si nibi irinajo yii ni ipo ẹlẹbẹ, mo bẹ awọn agbagba ẹgbẹ pe ki ẹ ba mi fọwọsowọpọ lati bẹ wọn ki wọn jẹ ki ogun ki o mi, nitori ko si nnkan ti ẹgbẹ maa gba ninu wahala nla yii.

Ko si are ti mo fẹ da fun eeyan kan debi pe maa da wọn lẹbi, nitori ija to ba ti n wa  nilẹ lati bi ọdun mẹwaa si mọkanla, o yẹ ki ẹbi ija naa ti kari. A o le jẹ ekuru ko tan, ki a tun maa nawọ ẹ sawo.

O dami loju pe ija naa yoo pari laipẹ

Lagbara Ọlọrun ko si nnkan to n ni ibẹrẹ ti ko ni opin.Ni erongbatemi ẹgun ti gun PDP, wọn si ti ṣetan lati yọ.Nitori pe kin ni yatọ si pe ki wọn kan darukọ eeyan meji si mẹta kan,gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ ọkan wọn ti papọ ṣoju kan, ẹni ti yoo yanju nnkan to wa nilẹ yii laaarin ẹgbẹ lapapọ ati ile-ẹjọ.

Mo si nigbagbọ pe erongba ileejo lori eto  ẹgbẹ, ko duro ṣoju kan, ibi to wa ni 1999 lati baa ni 2007, to jẹ pe bẹẹ ni ofin ko ni ni ki APC  Zamfara maa ni oludije, ki Rivers maa ni oludije, o daju pe eyi to n ṣẹlẹ nipinlẹ Ogun, ofim maa fori ẹ ti sibi kan.

To si jẹ pe ko ni kọja ibi ti igbimọ ijọba lapaapọ n fẹ. Asẹyinwa asẹyinbọ bi a ba fẹẹ ṣe daadaa nipinlẹ Ogun, a ni lati bẹ wọn ni pe ki wọn bara wọn sọrọ nitori ọmọọya ni wọn.

Ko si nnkan to le, ti ko le rọ, ki onikaluku mọ bi yoo ṣe ṣe, emi ni ọga, mi o gba, o tẹriba fun mi, mi o ni jẹ ko o lọ, awọn to n dẹgbẹ laamu ko ranti daadaa pe meloo ni ibo wọn gan-an paapaa ti a ba ni ki a kaa, awọn eeyan ilu ni wọn fi ibo da awọn eeyan lọla.

Ni temi, ọjọ ọla PDP o dara, boya yoo wa de ipinlẹ Ogun, o ku si wọn lọwọ, nitori pe mo mọ pe awọn olugbe PDP ti Ogun, n ṣe yamayama, ki wọn ma dibo fẹni ti wọn n fẹ ninu ẹgbẹ mii in, a ti ri bẹẹ.
Wọn gbọ o, wọn ko gbọ o, ijọba tiwa-n-tiwa nipinlẹ Ogun n tẹsiwaju.


No comments:

Post a Comment

Pages