Eyi tun ni diẹ lara ọrọ ti Bayọ Dayọ bawọn oniroyin sọ nipa Buruji Kashamu.
Aseyọri ẹgbẹ naa lati bi ọdun mẹjọ sẹyin
Nnkan taa mọ pe ẹ maa beere naa niyẹn nigba taa ti mọ pe ọdun
mẹjọ yẹn, ẹ o beere pe nibo la ba iṣẹ de lọdun mẹjọ,ibi taa ba iṣẹ de naa ni ifasẹyin ti Buruji fun
wa, oun naa la sọ pe a gbọdọ wa ọna bo ṣe maa dara ka to kuro ni ọfiisi.
Nigba ti mo maa sọrọ yii, ẹni to mu silẹ gẹgẹ bi alaga
bayii, Bamgboṣe, mo pee, lẹyin tawa oloye ti pinnu tan pe a fẹ kọ lẹta si lọya
pe a o ṣẹjọ mọ, ni ṣe ni a fẹẹ ṣe irẹpọ laaarin wa mo pe Bamgboṣe, O wa sọdọ
mi, mo ni ko mu ẹlẹri da ni, o mu eeyan kan da ni.
Mo si baa sọrọ pe ta o ba sẹjọ mọ, ti gbogbo wa ba wa ni
irẹpọ,igba yẹn ni ẹgbẹ wa yoo to ni ilọsiwaju o, o si gba. A jọ sọrọ ni
itubiinubi, nigbẹyin gbẹyin boya nitori wọn maa gbe mọto fun un, lo fi lẹ ti wọn
jọ lọ mu gbogbo ẹ ti wọn daru lọhun.
Ṣugbọn ẹni to pe dani to jẹ ẹlẹri a le pe ki ẹ gbọ ohun
taa jọ sọ, igba ti Bamgboṣe dele ni alẹ lo pe mi pe, ọrọ ti mo ba oun sọ pe a
maa wa nirẹpọ awọn ẹgbẹ naa ko mu owo wa ni.O ṣa ni iye nnkankan taa le pin, mo
ni emi ko ba nnkan pinpin lọ si ọdọ wọn, ka pari ọrọ ka di ọkan ni mo ba lọ.Kawọn
igun mejeeji gba oye,nnkan taa ba lọ niyẹn, a fi bi a ṣe n gbọ oriṣiriṣi.
Mi o gbowo kankan, Buruji n parọ ni ko soun ti ko le sọ,ko si nnkan ti
ko le ṣe to ba fẹẹ ba teeyan jẹ, Ọlọrun ko nii jẹ ko ba temi jẹ.gbogbo ọrọ to n
sọ pe mo ṣe bayii, mo ti gbe e lọ sile-ẹjọ,ọrọ yẹn ọpọlọpọ ẹ mi o ni le sọ nibi
bayii lonii.
Nigba tigbẹjọ ba bẹrẹ yoo wa sọ nibi ti mo ti gbowo, o ni
oun ni ẹri ẹ, gbogbo ẹ naa ni yoo gbe kalẹ.Ṣugbọn Buruji Kashamu lo pe ara ẹ ni
o, tabi Ẹsọ Jinadu tabi Moshafau Oshodipẹ, ẹ ba wa bẹẹ ko jẹ ki ẹgbẹ PDP ko ni
idagbasoke, ko jẹ ka alaafia jọba.
Ṣe lo ni oun yoo da ẹgbẹ naa duro ni ti ko ni wulo fẹnikẹni,
o sọ yẹn femi alaga, o si fẹ ki n ba ẹ ṣe pọ,bo tilẹ jẹ pe iwọ lo ṣe ti mo debẹ,
ọjọ teeyan ba lọ wa igi ninu oko, to ko sinu ina,igi yẹn ti di ọga ẹ, ko tun le
gba mu mọ. Buruji Kashamu, ko le gba mi mu mọ.
Loootọ oun lo ṣokunfa bi mo ṣe di alaga, mo si ti fun ni ọwọ
ẹ, bo ṣe tọ ati bo ṣe yẹ ṣugbọn nnkan to fẹẹ ṣe lo fẹẹ ṣe owo lo n wa kaakiri.
Ko fẹ ṣe ẹgbẹ, to ba fẹẹ ṣe, ko lọ sọdọ OGD, ki wọn kọ bi wọn ṣe n ko awọn
eeyan jọ, ko lọ sọdọ JMK, awọn to le kọ niṣẹ niyẹn o.
Ipo tawọn
agbaagba ẹgbẹ wa lori ọrọ yii ati ọna abayọ.
Ọna abayọ naa ni mo ti sọ fun yin yẹn, nigba taa ni awọn
oloye ẹgbẹ nipinlẹ Ogun, mẹtadinlọgbọn ni wa, mẹrinlelogun lo ti lọ sọdọ Lado,
ti a ku mẹta ninu awọn taa dibo yan ni ọdọ wa.
Ti Sẹmiu Ṣodipọ tun ti lọ, a ku meji, emi ati igbakeji oluyẹwe owo wo iyẹn Bamgboṣe,
tori ipo to wa tẹlẹ niyẹn.Bo ṣe ṣẹlẹ si awa oloye ẹgbẹ bẹẹ lo ṣẹlẹ sawọn
agbaagba ẹgbẹ, gbogbo wọn lo ti wa lọdọ
Lado, agba ẹgbẹ mẹta lo ku ninu awọn to le ni ọgọrun-un.
Gbogbo wa la ti ṣepade pe ka papọ, tawọn Abuja ba si ti fọwọ
si, ki wọn jẹ ki Kashamu maa lọ si ẹgbẹ ti yoo ti maa paṣẹ fun wọn. O kan n
fori wa gba parọ ni,ẹ ko le ri orukọ ẹ lawọn ẹjọ to pe pe o lọ n ja, ori awọn ọmọlọmọ
lo maa gbe sibẹ, o ti bẹrẹ si ni gbe ori Bamgboṣe sibẹ bayii. O ti ṣe bẹẹ femi
naa ri ṣugbọn ti mo yari , ti mo ni mi o le ṣe agbalagba ni mi.
Eyi to n ṣe nita gbangba niyẹn, eyi to n ṣe nile aṣiri ẹ
a maa tu,bo ṣe n gbowo ilẹ lọwọ ẹni mẹrin papọ,aburo mi Ibilọla Ṣolaja, owo to
gba lọwọ ẹ le ni ọgọrun-un kan miliọnu, to ni oun maa ta ile ati ilẹ fun,ti ko
ri nnkankan yọju ẹ sita. To ba fẹ ko lọ kọọtu pe mo sọ o.
Awọn to ra ẹran ileya lọwọ ẹ ati maalu, mọla yẹn wa n
sunkun lẹnu ọna mi lojoojumọ, sọwedowo to fun lọya yẹn wa lọwọ mi nibi yii. Oun
ni mo fi han yin yii, miliọnu mẹta ati ẹgbẹrun lọna ọọdunrun naira.
Mọla yẹn ko ri owo yẹn gba titi di akoko taa n sọrọ ẹ yii
o, to ba maa sọ, a ni ẹnikan lo le oun, toun ko wale lati wa ṣe itunnu awẹ, ni ṣe
lo sa o, nitori pe nibo lo ti maa ri ẹran mii in gba lọdun yii.
Mọla mu sọwedowo naa lọ si banki ti ko rowo gba, ko ti
sanwo ẹran ọdun to kọja, ṣe ẹran ọdun yii, nibo lo ti fẹẹ gbawin tọdun yii. ọrọ
pọ ninu iwe kọbọ, ẹ ẹ ma jẹ ki Ọgbẹni yẹn tan yin jẹ o.
Ẹni to maa fori ẹ gba parọ lo n wa kaari, ko si le tu
irun kankan lara mi. Ẹgbẹ lo pa emi ati ẹ pọ a si ti jọ ṣẹgbẹ naa.
No comments:
Post a Comment