Alaga fẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ogun, Onimọ-ẹrọ Bayọ Dayọ, tun ti tan imọlẹ si pe Ọgbẹni Abayọmi Olufẹmi Arabambi, to jẹ alaga fẹgbẹ oṣelu Lebo nipinlẹ Ogun, ni Buruji Kashamu, ran lati maa ṣiṣẹ ibi, nitori mẹsenja rẹ ni, ati pe ibi to ba ti rowo ibẹ lo n lọ.
O sọrọ yii lakooko to n bawọn oniroyin sọrọ niluu ilu Ijẹbu-Igbo,
o ni alaga ẹgbẹ oṣelu Lebọ naa tun jẹ ẹni
to fẹran ounjẹ, O ni oun ni alaga ẹgbẹ
olori ọdẹ gbogbo ilẹ Ijẹbu,ọjọ tawọn ọdẹ wa ṣe ipade lọdọ oun o wa.
O ni ‘’Koda wọn fun ni ẹran igbẹ, o jẹun lọjọ naa, o gbe ọmọbinrin
kan wa, to fiyẹn silẹ ninu mọto, toun goke wa, to wa jẹun, ounjẹ lo n jẹ
kaakiri, ko si nnkan to ṣe ju pe ibi ti yoo ba ti jẹun lo n wa kaakiri’’.
‘’Emi o ki n sọ nnkan ti ki i ṣotitọ o, ẹ sọ fun pe mo ni lọjọ ti mo n ṣe ipade ọlọdẹ, o
wa sibẹ wa jẹun. Ounjẹ lo n wa kaakiri, oun naa lo si wa de ọdọ Buruji, ti
Buruji ba fẹẹ ṣiṣẹ ijanba, a ni ki Arabambi ko lọ sọ’’.
“Ṣebi oun lo sọ fun Buruji pe emi ti lọ sọdọ Lado, o ni
Lado ti ni arun korona fairọọsi, pe emi Onimọ
Ẹrọ Bayọ Dayọ naa ti ni korona o, emi to ni mo ni naa lẹ jokoo ti yii o, eyi to
ti sọrọ naa ti ti ọsẹ mẹrin o, kin ni a wa fẹ sọ’’.
Bayọ Dayọ tun sọ siwaju pe alaga ẹgbẹ oṣelu Lebọ ọhun jẹ ẹni ti wọn gba lati maa ṣiṣẹ ibi,,tiṣẹ ibi
kan ba wa nibi kan, wọn a pe pe ko wa, yoo si beere pe elo ni wọn yoo foun.wọn
yoo sọ iye ti yoo gba, wọn a wa ni bayii ni ko lọ sọ nibẹ, o niṣẹ to n ṣe
kaakiri niyẹn, o ki i ṣe fẹgbẹ lebọ
nikan gbogbo ẹni to ba ti nilo ẹ lo n ṣe fun..
No comments:
Post a Comment