Beeyan ba ro pe wahala to n bẹ silẹ ninu ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ogun, laaarin alaga ẹgbẹ naa, Oloye Bayọ Dayọ ati Sẹnetọ Buruji Kashamu yoo pari, irọ patapata gbaa ni, nitori ojoojumọ ni o n burẹkẹ si, tọpọ aṣiri tawọn eeyan ko mọ laaarin awọn mejeeji bẹrẹ si ni tu jade.
Bo tilẹ jẹ pe lọṣẹ to kọja ni Buruji Kashamu pe ipade oniroyin nibi to ti
fawọn ẹsun kan Bayọ Dayọ lori ẹgbẹ naa. Ni bayii, Bayọ Dayọ naa ti sọ tẹnu ẹ,
apa kin- in- ni ree ninu ọrọ to ba wa sọ.
Mo ti wa ninu ẹgbẹ
oslu PDP latigba ti wọn ti daa silẹ, mi o si figba kankan kuro nibẹ
titi di akoko yii. Ipo akọkọ ti mo kọkọ gba nibẹ lọdun 1999 ni igbakeji akọwe
oluṣeto ẹgbẹ fun ipinlẹ Ogun, latigba naa ni mo ti wa n goke lọ diẹdiẹ, titi mo
fi de ipo alaga to ṣẹṣẹ n pari lọ
Emi ni alaga titi dgba tawọn oloye mii in fi maa de bẹ,
ko si oloye to le de bẹ laijẹ pe emi ati akọwe ẹgbẹ fọwọ si, ohun ti idajọ to
wa lọwọ wa sọ niyẹn, bi ẹnikan ba wa sọ pe oun ni ọna aburu kan to le gba, awọn
oloye ẹgbẹ lapapọ ti sọ fun mi pe emi ni mo wa nibẹ, titi tawọn yoo fi yan
oloye mii in tabi igbimọ fidihẹ, gbogbo ọrọ yii ti wa nile ẹjọ kii ṣe nnkan ta
le mẹnu lọ titi.
Ipo ti ẹgbẹ oṣelu
PDP wa nipinlẹ Ogun
Ọrọ ọjọ ọla ko le dara ko le dara taa n ṣe lọ lo n bi Ọgbẹni
to gbe ara ẹ ni Buruji Kashamu,Muṣafaru Ṣodipẹ lemi mọ lorukọ ẹ to n jẹ nileewe
to lọ, to ka to fi de iwe kẹrin alakọbẹrẹ ko to salọ.
Nigba to kuro nile lo tun pe ara ẹ ni ẹṣọ Jinadu l’Ekoo,
o tun wa sọ pe oun ọmọọba, mi o mọ ilu to ti jẹ ọmọọba naa si o, ṣugbọn mo mọ
pe kii ṣe Ijẹbu Igbo yii o.Boya wọn fun loye ọmọọba niluu ibikan mi o le sọ.
Ṣugbọn awuyewuye to n ṣẹlẹ lọwọ bayii ni pe awa fẹẹ ko dara
ki gbogbo ẹgbẹ ko papọ Buruji ko fẹẹ ko
dara, o fẹẹ ma lo ẹgbẹ naa gẹgẹ bi ohun elo lati maa ṣiṣẹ, PDP ki sohun elo
lati maa fi ṣiṣẹ o, ẹni to ba mọ Muṣafau ko sọ fun PDP kii sohun iṣẹ, ibi tawọn
eeyan ti fẹẹ ka ṣoriire, tawọn eeyan n rọ mọ wa.
Ki ẹgbẹ yii le papọ atọtun atosi, ki wọn di odindi, oun
la duro fun, to si wa duro nibi kan pe a gbowo, ṣe a rẹni to sọ pe owo oun sọnu
ẹnikan wa ji owo oun, ko si, Buruji funra ẹ to n gbowo nigba to tiẹ gba apoti,
to loun fẹẹ ṣe gomina, to gbowo lọwọ oludije gomina mii in kiri.
Gbogbo eeyan sọ nigba naa pe a o fẹẹ ṣe gomina yii, ṣe la
n tan ara wa, emi o gbagbọ, igba ti wọn ṣẹṣẹ fi awọn ẹri ibi to ti gbowo lọtun
losi ninu ẹgbẹ mii in, nigba ti mo rii ni mo ṣẹṣẹ gbagbọ, ki ẹgbẹ yii le
dara,ni a ṣe sọ pe ka papọ, taa ba papọ, taa di odidi.
Gẹgẹ bi alaga ẹgbẹ, mo ni ẹtọ lati lọ si gbogbo igun to
wa ninu ẹgbẹ lati bẹ awọn to ba yẹ, ki wọn fawọn mọra, ki wọn ri pe a di ẹyọ
kan ṣoṣo, ko ma si pe enikan maa wo, iyen leto taa n ṣe, ti ko tẹ Buruji lọrun.
Nitori tawọn aṣaaju ninu ẹgbẹ ba to mẹrin, marun un, ẹgbẹ
maa fi dara si ni, ṣugbọn Buruji ro pe oun nikan ṣoṣo ni aṣaaju, nitori ẹ lo ṣe
n sare gba awin mọto to n gbe kaakiri pe kawọn eeyan wa maa gba lati fi fawọn mọra,
ọna ko si nibẹ.
Gbogbo awọn aṣaaju nipinlẹ Ogun la bẹ, ki wọn pada bọ, ko
ri bo ṣe ri tẹlẹ, nigba ti Buruji maa de sinu ẹgbẹ wa yii, iwe ti wọn fun wa
lati Abuja, ti wọn ni ki wọn jẹ kẹgbẹ di ọkan, ki wọn pin fun tawọn ti OGD ati
JMK, ko si ti Buruji nibẹ.
JMK lawa wa o, nigba taa debẹ, taa lọ ṣe ipade nile Baba
wa kan ni Eko, ni Buruji ti wa ba wa pe gbogbo nnkan ta n sọ ko muna doko o, o
lọ si kootu pe awọn agbaagba ti fẹnu ko pe awọn oloye ti wọn fẹẹ mu silẹ re.
Ko si agbaagba to fẹnuko, funra ẹ lo mu awọn to fẹẹ fi
sibẹ, to sa lọ ba Baba wa Ọbasanjọ, to lọ parọ fun wọn. O gbiyanju lọdọ Baba
tiyẹn gba pe o jẹ eeyan to fẹẹ ṣe ododo, laimọ pe ọgbọn lo fẹẹ lo, nigba to si
gba nnkan to fẹẹ gba nipinlẹ tan, o kẹyin si Baba, to n ṣe nnkan to wuu.
Ohun naa la wa loko ẹ doni o, ni 2011, a gbe apoti, a ni
ile igbimọ aṣofin mẹsan an, ni 2015, a ni marun un, nigba to di 2019, lakooko
ti Buruji, ẹyọ kan soso laa ni o, ẹni to gbe apoti pe oun fẹẹ ṣe gomina, ṣe
lemi tiẹ n bawọn ọmọ ẹgbẹ mii ja pe wọn gbowo lọ, wọn ko ṣe daadaa, ẹmi o mọ pe
ko fẹẹ ki wọn ṣe daadaa, o fẹẹ ki wọn gbowo yẹn ki wọn lọ pin.Nitori o gbapoti
gomina, o tun lọ bawọn to tun dije pẹlu ẹ, to gbowo lọwọ wọn, kin ni ka ti pe o
fẹẹ ba ẹgbẹ jẹ ni o. Irọ lo n pa pe mo gbowo lọwọ ẹnikẹni, mi o gbowo o.
Kin ni Buruji mọ
nipa gbongbo ẹgbẹ
Kin ni oni iwe kẹrin alakọbẹrẹ mọ ti wọn n pe ni gbongbo ẹgbẹ,
iyẹn structure, nnkan ti wọn n pe bẹẹ ni gbogbo awọn agbaagba ẹgbẹ ati gbogbo
awọn eeyan ti wọn da ẹgbẹ naa silẹ, bi ẹ ba maa mu gbongbo ẹgbẹ silẹ, ẹ o pe
gbogbo awọn agbaagba jokoo, lati mu ẹnikọọkan silẹ to yoo ṣoju yin.
Ṣugbọn Buruji ro pe oun loun ni, yoo maa fọwọ gbaya pe
oun loun ṣe e, owo wo lo fi ṣe, ṣe lo n gba lọwọ rango to n fun tango,ko si owo
kankan nibi kan to fi n ṣe nnkankan, gbogbo nnkan to ṣe, o ṣe daadaa nigba naa
taa ro pe yoo ṣe daadaa kanlẹ.
Ile mi ni mo jokoo nibi to ni ki n wa jẹ oludamọran ẹ, iyẹn
ajọ ọmọ-ilu, mo si ni mi o le wa o nitori wọn ni ẹ n gbe posi silẹ, tẹẹ maa fi
bura, ti wọn maa sun sibẹ, emi o si le bura fun eeyan ninu aye yii, lo wa ni ta
lo sọ pe kẹyin bura, ẹ ẹ maa bọ baba.
Bi mo ṣe de ọdọ ẹ niyẹn o, mi o bura fun o, ẹni ti ko ba
eeyan mulẹ n jẹ o le dalẹ ni.Mi o ba Buruji mulẹ o, debi pe maa dalẹ ẹ, Nigba
ti mo fi n jẹ oloye ni PDP, oun ṣi wa ni ọgba ẹwọn lo ṣi wa niluu oyinbo. Ko
tii de lati ọgba ẹwọn nigba naa o, nitori naa o ba mi ninu ẹgbẹ naa ni, ki i ṣe
emi ni mo ba nibẹ, ọga ẹ ni mo jẹ ninu ẹgbẹ naa.
Bi ẹ ba gba Buruji Kashamu laye lati wọnu ẹgbẹ yii pads ṣe
lẹ fẹẹ daru patapata o,emi ti ṣe ọdun mẹrin to yẹ ki n ṣe, ki n to pada wa
sile, ẹ ba mi bẹ Buruji, gbogbo ẹyin ọmọ ipinlẹ Ogun, ko ma wa pa mi mọle o. Ko
jẹ ki n gbadun ifẹyinti mi o,
Ọmọ mi to fẹsun
kan
Buruji funra ẹ ni jaguda paali, Muṣafau Ṣodipẹ, Ẹṣọ Jinadu,
ko sọ pe ọmọ temi jale awọn ọmọ ti mo kọ, ti wọn gbọ ẹkọ, ki ọmọ ti ko ka ju
iwe nẹrin alakọbẹrẹ kan maa sọ pe mi o kọ ọmọ mi lẹkọọ, ọmọ mi ko ṣe iṣiro owo
lọdọ ẹ o, ko si kọ lẹta si pe oun waṣẹ, ṣe lo pe e pe ko wa jẹ amugbalẹgbẹ oun
to si mu lọ si Eko, emi ki i mu ọmọ mi kankan lọ sile agba ẹgbẹ kan pe ki wọn
ba mi waṣẹ fọmọ mi.
Ẹni to n ṣe amugbalẹgbẹ to n san ẹgbẹrun lọna ọgọrun naira
fun loṣu, nigba to ṣẹṣẹ da Western Lotto silẹ,
lo sọ pe o fi kun owo ẹ, ọmọ yẹn ti ralẹ pẹlu iyawo ẹ, tiyẹn n taṣọ. Buruji
ti ran iyawo ẹ lọ si Dubai ti to ẹẹmẹrin to n ko dọla lati baa raṣọ bọ, ki lo fẹẹ
ja lole fun un. Ki lo de ti ko ti pariwo ẹ sita tipẹ, o ṣe jẹ akoko tiyẹn fiwe
silẹ fun un pe oun ko ba ṣiṣẹ mọ nitori wahala to wa nilẹ yii lo ṣẹṣẹ wa n
pariwo.
Nigba to fun niwee pe oun ko baa ṣiṣẹ mọ lo ṣẹṣẹ wa
pariwo pe oun yoo ṣe iwadii ẹ, pe o ralẹ sibi kan, o kọle sibi kan, ile taa n sọrọ
ẹ yii ti Arabambi to wa ni Lebọ, to fẹẹ ba PDP jẹ fun wa lọ sibẹ, o ni mansion
lọmọ mi kọ, ile yẹn ko pe pulọọti kan o.
Mi o ṣiṣẹ labẹ Buruji Kashamu o, to ni ẹẹdẹgbẹta miliọnu
kan mo ti gbe, iwe akaunti ẹgbẹ wa wa nibi, mo ni ki wọn lọ gba ni banki, ibi to
ti maa wa gbowo lọwọ wa ni ile ẹgbẹ wa, gbogbo ẹ lo wa nibi.
Gbogbo owo to gba lọwọ wa to miliọnu lọna aadọta naira,
igba to kọkọ wa, o gba miliọnu mẹwaa naira, to ba gbọ pe wọn fowo ranṣẹ si wa
tabi a ṣeto kan, oun i yoo wa gbowo naa. O wa ni emi gbe miliọnu lọna aadọta
naira.
Owo to pọju ni igba taa fẹẹ dibo lọdun 2015, owo yẹn lo pọ
ju,owo ta pa jẹ miliọnu lọna irinwo o le diẹ naira, oju ẹsẹ lati ko lọ si Abuja,
tawọn fi ere ti wa ranṣẹ, ọjọ keji to gbọ
pe owo ti de, lo de lo wa gba miliọnu lọna ogun naira, owo lọya atawọn owo mii
in, mo ni ki akọwe fun niwee sọwedowo, mo ni orukọ, wo lo fẹẹ fi kọ, o ni ọmọ
ilu Foundation. Owo PDP ni Buruji fi n ṣe Ọmọ Ilu Foundation.
APA KEJI N BỌ LAIPẸ
No comments:
Post a Comment