Onarebu Alaaji Saka Ahmed tọpọ mọ si lagọku Iṣara, to n
dije fun ipo alaga ijọba ibilẹ Ariwa Rẹmọ, nipinlẹ Ogun,ti rọ awọn asaaju ninu
oṣelu nipinlẹ Ogun lati ma ṣe sọ pe awọn ni eeyan kan ni pato lati dupo alaga
ijọba ibilẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu APC, ki wọn faye gba ibo abẹle wọrọwọ ti ko ni mu wahala kan kan jade.
Ọkunrin naa sọrọ yii lakooko to n ba oniroyin wa sọrọ
nipa erogba ẹ lati di alaga naa, o ni lọpọ igba lawọn Gomina atawọn aṣaaju ninu
oṣelu maa n paṣẹ pe dandan ẹni bayii lawọn fẹẹ ko di alaga ṣugbọn oun mọ pe
Gomina Dapọ Abiọdun ko le ṣeru ẹ.
O sọ pe ‘’ Loootọ iru ẹ ti n ṣẹlẹ si mi ni aimọye igba,
Bibeli sọ pe bi ko ṣe pe Oluwa kọ ile naa, awọn oṣiṣẹ n ṣe lasan ni, ẹbẹ taa n
bẹ awọn Gomina wa lakooko yii, emi o ro pe Dapọ le ṣe bẹẹ, ṣugbọn ka maa bẹ awọn
ọga wa, ki wọn faye gba ibo abẹle ti ko ni ni wahala ninu tabi ti wọn yoo paṣẹ
pe dandan bayii ẹni tawọn fẹẹ ko ṣe
niyii.Ki wọn ma gbe ẹni ti ko le lero lẹyin sita, nitori awa ni wọn yoo fẹẹ lo,
nitori wọn ko le ṣe nnkan buburu ka wa binu kuro ninu ẹgbẹ ko ṣe e ṣe’’.
O fikun ọrọ ẹ pe erogba oun lati di alaga ijọba ibilẹ ọhun
lati mu ilọsiwaju ati idagbasoke ba kansu naa ju bo ṣe wa lọ. O ni ‘’Gẹgẹ bi
oloṣelu, emi kii ṣe oloṣelu to n dan ẹnu, a jọ n gbe ni, mi o kii ṣe ara Eko
tabi Tokunbọ, akọkọ ni iwosan to peye, eto ẹkọ, omi, ọna, abo ati igbogun ti
ebi nijọba ibilẹ mi,awọn nnkan ti mo maa fi ṣe ti wa nilẹ, maa tun da ile alajẹsẹku
silẹ fawọn obinrin, ti wọn n ta worobo, bi ko ṣe ẹgbẹrun lọna aadọta naira si ẹgbẹrun
lẹna ọgọrun un naira la o maa yan wọon laisan owo ele.
Awọn eto ti mo ni fun ijọba
ibilẹ Ariwa Rẹmọ pọ, ki Ọlọrun ran mi lọwọ ti mo ba ti debẹ’’.
Saka Ahmed tun sọ pe
wọọdu kẹta ni oun ti wa ni Iṣara, ati pẹlu awọn ijakulẹ toun ti ba pade
latigba toun ti ba pade nidii oṣelu iyẹn ko ni koun fi silẹ nitori ninu ẹjẹ oun
lo wa.
O fi kun pe‘’Aimọye ipo ni mo ti di mu ninu ẹgbẹ oṣelu
latigba ti mo ti bẹrẹ, koda mo tun ti dije fawọn ipo bi aṣoju nile igbimọ aṣofin nipinlẹ Ogun lẹẹmeji ọtọọtọ
ṣugbọn tawọn alagbara ko jẹ ki n de bẹ. Mo tun dije fun alaga ijọba ibilẹ amọ
Ibikunle Amosun Gomina nigba naa tun lo agbara lati lo awọn oludije ẹ’’.
‘’Ṣe ẹ ri ẹni ti ẹjẹ
oṣelu ba ti wa lara ẹ, ko ki n su. Ẹ wo Baba wa Awolọwọ ti mo tẹle, pẹlu gbogbo
ijakulẹ to ri ko dẹyin nidii oṣelu to fi ku., nitori naa ko su mi, ko si ni rẹmi’’
O wa niṣẹ kan tawọn n ṣe lọwọ bayii nidii oṣelu lawọn n
pe ni ṣiṣe abẹwo, oun ti ṣabẹwo sọdọ awọn to jẹ aṣaaju wa,, awọn ọmọ ẹgbẹ ayawọn oloye ẹgbẹ. Nigba ti akoko ba
to ti wọn ba ṣi aṣọ nidii oṣelu, wọn yoo riṣẹ ọwọ oun..
O pari ọrọ ẹ pe ‘’Laarin emi atawọn taa jọ n dupo, ṣe ẹ mọ
pe iyọ kii yin ara ẹ, ohun to da mi loju ni pe lagbara Ọlọrun pẹlu atilẹyin
Anabi, awọn to ṣi jade bayii pe wọn dupo ọga wọn ni mo jẹ tawọn naa si mọ.Bi ẹ
ba beere mi lọwọ wọn, wọn a ni ọga awọn ni mi, wọn a fi silẹ fun mi ni. Ninu wọn
eyi ti mo tun kọ nipa oṣelu wa ninu wọn, Ọlọrun ko ni gba fun wọn, wọn a wọ ọla
mo ju awọn lọ, wọn a ju silẹ, nitori Baba wọn ni mi’’.
No comments:
Post a Comment