Arabinrin Ọnarebu Olufunmilayọ Iredee Ọginni, ti gba Gomina Dapọ Abiọdun lamọran lati ri pe o kọju mọ awọn nnkan to n ṣe lati le mu ipinlẹ Ogun goke agba, ko si ma ṣe gbagbe awọn ileri ẹ faraalu.
Obinrin naa
sọrọ yii lakooko to n ki Gomina ọhun ku ayẹyẹ ọdun kan to gbakoso iṣejọba
ipinlẹ Ogun ati bi ọjọ naa tun ṣe bọ si ayajọ ọjọọbi ọgọta ọdun to dele aye.
Ninu iṣẹ tobinrin
naa ran, lo ni oun ba aṣaaju ipinlẹ Ogun naa yọ fawọn aṣeyọri nla to ti ṣe
laaarin ọdun kan, eyi to ni o tumọ si pe loootọ ni ọkunrin naa wa lati wa gbe
ipinlẹ naa goke ju bo ti wa lọ.
O wa gba
lamọran pe ko fi ti ayajọ ọjọọbi naa tẹpẹlẹ mọ awọn iṣẹ to n ṣe laiboju wẹyin
ati pe ko jẹ ki eto abo ati ti ẹkọ ko jẹ pataki ju ninu gbogbo nnkan to ba n
ṣe. Nitori awọn meji ọhun wa lara awọn nnkan to ṣe koko fawọn araalu.
Bẹẹ lo ni ko jẹ
kijọba ẹ jẹ ti ọrẹ laaarin oun atawọn ilu, ko si yatọ gedegbe sawọn nnkan to ti
awọn isakoso ti wọn ti wa tẹlẹ ṣubu, ko ma jẹ ko gbe oun naa ṣubu. O fi kun ọrọ
ẹ pe gbogbo ohun to ba n ṣe ko maa fi ti Ọlọrun ṣiwaju, nitori oun ni
alatilẹyin ẹ titi di akoko yii.
Irede tun
ṣalaye pe ki Dapọ Abiọdun ri pe awọn to wa nigberiko naa jẹ awọn anfaani nla
ninu iṣejọba ẹ, nitori ọpọ wọn lo nigbagbọ ninu ijọba ẹ, ko ma si ṣe doju ti
igbagbọ naa.
O wa ṣadura pe
Ọlọrun yoo tubọ fun lọgbọn ati oye ti yoo fi tukọ ipinlẹ yii daadaa
No comments:
Post a Comment