Olu of Itori ba Gomina Dapọ Abiọdun ṣajọyọ ọjọọbi ọgọta ọdun ati ọdun kan iṣakoso ẹ nipinlẹ Ogun. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday 29 May 2020

Olu of Itori ba Gomina Dapọ Abiọdun ṣajọyọ ọjọọbi ọgọta ọdun ati ọdun kan iṣakoso ẹ nipinlẹ Ogun.


 
Olu-Itori tilẹ Ẹgba, Ọba Fatai Akorede Akamọ, ti ranṣẹ ajọyọ ọjọọbi ọgọta ọdun si Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiodun, bẹẹ lo tun ki fun ti ayẹyẹ ọdun kan to gbakoso ipinlẹ naa.

Ninu iṣẹ to ran naa lo ti sọ pe, Gomina wa ṣakoso lakooko tawọn araalu n fẹ iṣakoso rere nipinlẹ ọhun, eyi to si ti mu ayipada rere ba gẹgẹ bi aṣaaju rere to nifẹẹ awẹn eeyan ẹ lọkan.

Ọba naa tun sọ pe ‘’ Mo ranti ọjọ manigbagbe ti ẹ gba akoso, ti ayẹyẹ naa waye ni papa iṣere MKO Abiola gẹgẹ bi gomina ijọba tiwa-n-tiwa ẹlẹẹkarun mu ohun iwuri wa gẹgẹ bi ọmọ bibi ilẹ Rẹmọ’.

O ni ohun ayọ lo tun jẹ pe gbogbo ileri  Gomina naa lati ṣaaju wa de ilẹ ileri jẹ awọn amuyangan pẹlu awọn iriri toun naa ti ni gẹgẹ bi oniṣowo nla, to si tun mọ nipa okoowo daadaa.

O tun fi kun ọrọ ẹ pe gẹgẹ bi Ọmọọba, awọn ko ṣiyemeji kankan nipa ẹ bo tilẹ jẹ pe awọn alumọni ko fi bẹẹ pọ to ba nilẹ, ṣugbọn o lo gbogbo ọgbọn ati oye lori awọn eyi to ba lati le jẹ ki nnkan maa lọ nirọwọ-rẹsẹ.

Olu Itori wa ni awọn tun dupẹ lọwọ ẹ fawọn ọkan to ti nawọ si igbesi aye wọn, to n jẹ kawọn eeyan naa si ni ireti ninu aye yii.

O wa ni bi Gomina ṣe n ṣajọyọ ọgọta ọdun to dele aye, loruko oun, iyawo oun ati gbogbo awọn eeyan ilẹ Itori-Ewekoro awọn darapọ miliọnu awọn eeyan lagbaye lati ba a ṣajọyọ tawọn si tun ki fawọn aṣeyọri to ti ṣe lati ọdun kan sẹyin to ti gbakoso gẹgẹ bi gomina nipinlẹ Ogun.

O wa pari ọrọ ẹ pẹlu idaniloju pe oun ko ni figba kankan kẹyin ninu ifọwọsowọpọ ẹ ati pe ajọṣepọ naa yoo tubọ danmọran. Lẹẹkan si o tun kii ku oriire ibeji to n ṣe pọ lẹẹkan naa.

No comments:

Post a Comment

Pages