Ọnarebu Olufunmilayọ Iredee Ọginni ti gba awọn obi nimọran lati ri pe wọn tọju awọn ọmọ wọn lati ma jẹ ki wọn ko arun korona fairọọsi to gbode yii. Obinrin naa sọrọ yii lakooko to n bawọn ewe sajọyọ ayajọ ọdun ewe eyi to waye lọsẹ yii.
Lakọkọ naa, o loun
bawọn ewe naa yọ pe ayajọ ọdun yii ṣoju ẹmi wọn layọ ati alaafia, bo tilẹ jẹ pe
ko si ayẹyẹ ipejọpọ wọn nitori ti konile-o-gbele to n waye lọwọ fun ti korona
fairọọsi, iyẹn kofid 19.
O sọ pe ohun to
ṣe pataki lakooko yii ni pe kawọn obi ṣamojuto awọn ọmọ wọn, ki wọn ma baa lugbadi arun naa. O ni ododo ẹyẹ lati
ọrun lawọn ọmọd, to jẹ pe to ba ya wọn yoo ododo naa kaakiri aye.
Irede ni idi
niyii ti wọn fi gbọdọ fi ifẹ awọn ọmọ wọn sọkan wọn, o ni ohun alumọni to mu
yangan lagbaye tun ni awọn ọmọde jẹ. Kawọn obi ri pe wọn ṣeto nnkan ti wọn ba n
fẹ fun wọn lakooko.
Bẹẹ lo tun wa
rọ awọn ọmọde naa lati ri pe wọn la akoko ti wọn wa yii ki wọn fi lo igba ewe wn
daadaa, ki wọn ma ṣe si iwa hu si obi, ki wọn gba pe awọn ni adari wa lọjọ
iwaju. O wa gbdura pe ọpọ ẹ ni wọn ni wọn yoo ṣe laye.
No comments:
Post a Comment