Pẹlu bi Gomina
ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun ṣe n ṣajọyọ ọjọọbi ọgọta ọdun to dele aye
lonii ati ọdun kan to n gbakoso ijọba ipinlẹ naa, ẹgbẹ apapọ oṣelu IPAC ti
ranṣẹ ikini ku oriire si Gomina ti wọn si tun n ba ṣajọyọ.
Gẹgẹ bi atẹjade ti Asiwaju Adesina
Abdul-Lateef Adedamola, to jẹ alaga ẹgbẹ nipinlẹ Ogun, fọwọ si lorukọ ẹgbẹ ọhun
ni wọn ti ṣapejuwe Gomina yii bi oloriire to si ti ṣe aṣeyọri to pọ laaarin
ọdun kan to ti gbajọba yii.
Wọn ni ko si
awitunwi asan kankan nibẹ pe inu akoko naa dun nigba ti Gomina waye lọjọ ti wọn
bi saye, Ati pe apẹẹrẹ rere ni ayọjọ ọjọọbi ẹ, nitori o ni idi pataki to fi
waye pe Mesaya awọn eeyan dudu ti wa nibi.
Aṣiwaju Adeṣina
tun ṣalaye ninu atẹjade ẹ niru ayẹyẹ ọjọọbi Gomina Dapọ Abiọdun to pe ọgọta
ọdun, ẹgbẹ oṣelu IPAC ko ki oun nikan fun apẹẹrẹ aṣiwaju rere to jẹ bẹẹ ni wọn
sọ pe awọn tun ki awọn eeyan ipinlẹ Ogun pe wọn ni akọni ẹda eeyan to ti mu
igbe aye irọrun bawọn to n dari laaarin oṣu mejila to ti depo to wa bayii.
Wọn ni iyalẹnu
lo tun jẹ pe ayajọ ti wọn fi ayẹyẹ ọdun dẹmokiresi si ni Dapọ Abiọdun tun ṣe ọjọọbi, o ni
awọn ko le sọ boya nitori ẹ gan-an ni wọn ṣe fayẹyẹ ijọba tiwa-n-tiwa si.
IPAC ni pẹlu ọgọta ọjọọbi ẹ, awọn aṣeyọri
ẹ tun fihan pe ọkunrin naa jẹ ẹni to ni ibẹru Ọlọrun, to si tun fi ti Ọlọrun
ṣiwaju gbogbo nnkan to n ṣe. A fi bi idan lawọn akọsilẹ iṣẹ to ti ṣe nipinlẹ
Ogun si n jẹ fawọn eeyan ẹ, to jẹ aṣaaju fun.
IPAC tun mẹnuba diẹ lara awọn
aṣeyọri Gomina ọhun laaarin ọdun kan, eyi ti wọn lo ṣe nipa eto ilera, ẹkọ, ọna
atawọn nnkan mii, eyi tawọn fi gba pe o ni ero rere fawọn eeyan ipinlẹ Ogun.
Bẹẹ ni wọn tun
mẹnuba ilakaka ẹ lati gbogun ti arun korona fairọọsi, to ti n ba orileede yii
finra, ti wọn lo ti mu ọpọ ẹmi awọn eeyan lọ, wọn wa gbadura pe bi Ọlọrun ba ṣe
n lọra ẹmi ẹ lati tun ṣe ọpọ laye bẹẹ naa ni yoo tun ni ọpọ aṣeyọri ju eyi to
ti wa nilẹ tẹlẹ lọ gẹgẹ bi Gomina.
No comments:
Post a Comment