Aiṣododo lo mu ifasẹyin ba ijọba tiwa-n-tiwa lorileede yii-Ọnarebu Moshood Salvador. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday 28 May 2020

Aiṣododo lo mu ifasẹyin ba ijọba tiwa-n-tiwa lorileede yii-Ọnarebu Moshood Salvador.




Agba oloṣelu nni ninu ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Eko, Ọnarebu Moshood Adegoke Salvador, ti sọ pe o digba ti ododo ba bẹrẹ si ni jọba lorileede yii ni mundunmundun ijọba tiwa-n-tiwa iyẹn Dẹmokiresi yoo to tẹ wa lọwọ.

O sọrọ yii lakooko to n ba oniroyin wa sọrọ lori foonu nigba ayẹyẹ ijọba tiwa-n tiwa ti yoo waye yii, o ni lọpọ igba ni ifasẹyin ti de ba wa lorileede yii nipasẹ aiṣododo awọn aṣaaju wa.

O ni o ṣe ni laaanu pe ilẹ wa Naijiria ko ba ti goke ju bayii lọ nipa ijọba tiwa-n-tiwa ṣugbọn awọn oloṣelu wa ti ba nnkan jẹ jinna, ayafi ti a ba tete wa atunṣe si ki nnkan ba le rọgbọ.

Bẹẹ lo ni eyi tawọn araalu naa n fa nibẹ lo jẹ bi afọwọfa nipa bi wọn ko ba ti fun wọn lowo, wọn ko ni dibo,idi niyii tawọn oloṣelu naa fi maa n jẹ gaaba le wọn lori lẹyin ti ọwọ wọn ba ti tẹ nnkan ti wọn n wa tan.

Ẹni to ti figba kan jẹ alaga PDP tẹlẹ nipinlẹ Eko, tun ṣalaye pe ki iru nnkan bayii ma ba maa waye lawon ṣe da ẹgbẹ kan ti wọn pe ni Conscience Forum silẹ, eyi to da lori ẹri ọkan nibi tawọn ti maa n kọ wọn bi wọn ṣe le maa ṣododo lori nnkan ti wọn ba n ṣe.

O ni ọrọ toun sọ yii ko yọ ẹnikẹni silẹ ninu oṣelu nitori gbogbo won bakan naa ni wọn, ododo ti sọnu ninu iwa wọn, ẹtan si ti pọju ti wọn tan awọn araalu.

O ni Conscience Forum yii tun dabi ile idanilẹkọọ nibi ti wọn ti n kọ nipa bi ọjọ ọla yoo ṣe dara nidi oṣelu.O wa gba awọn oloṣelu nimọran lati maa ṣootọ lori gbogbo nnkan ti wọn ba n ṣe.

O ni apẹẹrẹ nla ni ti arun korona faiọọsi to tan kaakiri gbogbo agbaye, ẹkọ nla lo ni o fi kọ wa pe ile aye yii ko jẹ nnkan, o ni ẹ wo iye awọn to ti ba iṣẹlẹ naa lọ, awọn olorukọ nla to ti baa rin.O ni bi igbe aye mẹkunnu yoo ṣe dara lo yẹ ko jẹ wọn logun julọ.


No comments:

Post a Comment

Pages