Idunnu lo ṣubu layọ fun Aarẹ ọna kakanfo
ilẹ Yoruba, Iba Gani Abiọdun Ige Adams, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ana, nigba ti
iyawo ẹ, Ayinba Mojisọla Adams, bi ibeji.
Gẹgẹ bi atẹjade
ti Ọgbẹni Kẹhinde Aderẹmi, to jẹ oludamọran pataki fun Iba Gani Adams nipa
iroyin fi sita lo ti ṣalaye pe ọsibitu aladaani kan to wa niluu Eko, ni obinrin
naa bimọ si, iyẹn ọkunrin kan ati obinrin kan.
O fikun ọrọ ẹ pe alaafia ni iya
atawọn ọmọ naa, o wa fi idunnu ẹ han si Ọlọrun fun oore ati ẹbun nla ti wọn ri
gba yii.
Atẹjade naa lọ bayii " Pẹlu
afikun ibeji ti Ọlọrun fi ta idile mi lọrẹ, inu mi dun pe Ọlọrun tun ṣe oun
iyanu fun mi paapaa julọ lakooko taa wa yii, mo fi ọpẹ fun Ọlọrun pe o ṣe nnkan
ti wọn ro pe ko le ṣe e ṣe’.
O ni oun dupẹ lọwọ gbogbo awọn eeyan
ti wọn ba oun yọ latigba ti oore nla naa ti wa de ọdọ oun, o loun dupẹ gidigidi
fun Ọlọrun. A gbọ pe latigba ti iroyin naa ti tan ka lawọn eeyan fi rọ wọ ile ẹ
to wa ni Omole Phase 2 nibi ti Aarẹ Ọna kakanfo
n gbẹ.
|
No comments:
Post a Comment