Alaaji Sarafa Tunji Iṣọla, Baba Adinni nipinlẹ Ogun ati ni gbogbo ilẹ
Yoruba to fi mọ ipinlẹ Delta ati ti Edo ti ranṣẹ ibanikẹdun lorukọ gbogbo
igbimọ Imaamu ati Alfa si ẹbi Imaamu ilẹ Ẹgba,
Sheikh Liadi Ayinde Orunsolu.
Gẹgẹ bi lẹta ti Baba Adinni naa fi
silẹ fawọn ẹbi Ọrunṣolu ni wọn ti ṣapejuwe Baba naa gẹgẹ bi ẹni to fi igbe aye
ẹ silẹ lati gbe ẹsin musulumi ga, tawọn ipa rere to ko nigba to wa laye ko le
parẹ ninu itan.
Imaamu Ọrunṣolu
to ku ni ẹni ọdun mejidinlọgọrun ni Alaaja Sarafa Iṣọla to ti figba kan jẹ
minisita lorileede sọ pe titi aye lawọn yoo maa ranti agbẹsin ga naa nitori bo
ṣe jẹ ki irẹpọ ko wa laaarin gbogbo musulumi nipinlẹ Ogun ati nilẹ Yoruba
.
O sọ pe ‘’ Opo kan ni Sheikh Liadi
jẹ ti a ko le gbagbọ, nitori oun gan-an ni isọkan, to jẹ ki ifọwọsowọpọ wa
laaarin awa musulumi nipinlẹ Ogun ati nilẹ Yoruba.
Sheikh Liadi Orunsolu, ẹni to jẹ
aarẹ ẹgbẹ fun gbogbo igbimọ imaamu ati Alfa nipinlẹ Ogun nigba to wa laye ni
wọn tun sọ ninu lẹta naa pe Ọlọrun fun lẹmi ọgbọn, imọ ati oye to fi n dari
awọn ni gbogbo igba to wa laye.
Bẹẹ ni Ṣarafa
Iṣọla tun fi kun pe awọn yoo maa ranti imaamu ọhun pẹlu awọn ipa ẹ lori ọrọ ẹlẹsin
de nipinlẹ Ogun ati nilẹ Yoruba ati pe aṣeyọri awọn iṣejọba nipinlẹ yii, o
lawọn ipa to ko pẹlu,
O ni gbogbo ipinlẹ Ogun ni wọn padanu
Imaamu ilẹ Ẹgba naa nitori awọn iṣe rere to ṣe, o wa gbadura pe ki Ọlọrun tẹ si afẹfẹ rere, ko si
mu aiṣedede ẹ kuro, bẹẹ lo tun gbadura pe ki Ọlọrun fawọ ẹbi atawọn musulumi
nipinlẹ Ogun ni ẹmi irọju ati igbagbọ lati fi le gba fun Ọlọrun.
Ọjọ Iṣẹgun,
Tusidee, ni Baba naa jade laye, ti wọn si ti sinku ẹ nilẹ ẹ
No comments:
Post a Comment