Oloye Bayọ Dayọ to n murasilẹ lati fipo alaga ẹgbẹ oṣelu PDP silẹ nipinlẹ Ogun ti sọ oun ṣetan lati tu gbogbo aṣiṣe Buruji Kashamu sita, to ba fi le kọwọ bọ oun lẹnu, nitori lai kekere loun ti mọ ọn. Ati pe oun ti murasilẹ lati pe e lẹjọ fun ibanilorukọ jẹ.
Ọkunrin naa sọrọ yii lakooko to n ba oniroyin wa sọrọ
lori ẹsun ti Kashamu fi kan an pe o n wọna lati gba ẹmi oun, o ni eyi ti ẹni to
ti figba kan jẹ aṣoju nile igbimọ aṣofin niluu Abuja, fun ẹkun Ogun East naa n ṣe
ti kọja ọrọ oṣelu, nitori o ni to ba jẹ oṣelu ni o ṣi le niyanju lọjọ iwaju.
Alaga naa sọ pe ‘’ Eyi ti Buruji n ṣe yii kii sọrọ oṣelu
mọ, to ba jẹ ọrọ oṣelu ni irẹpọ ṣi le wa lọjọ iwaju, ṣugbọn o ti faa ko ja
patapata, ṣe ẹ mọ pe mi o sọ nnkankan, mi o dahun,mo mọ Buruji lati kekere,
latigba ti wọn ti bi ni mo ti mọ on, gbogbo
aṣiṣe to ti ṣe tẹlẹ, ko si eyi ti mi ko mọ nibẹ’’
‘’Amọ agbalagba ni mi, agbalagba ko kii sọrọ tan, mo si
ti pe ọkan lara awọn ọmọ ẹ, pe ko ba ọga ẹ sọrọ, ibi to n ba ọrọ bọ ko sọrọ nibẹ
o, eeyan gbọdọ ro nnkan daadaa ko to ṣe e. Mi o fẹ sọ nnkankan o, ṣugbọn to ba
tọwọ bọ mi lẹnu ki ẹnikẹni ma da mi lẹbi o’’
Bakan naa lo tun ṣalaye siwaju pe oun ti lọ si kọọtu, oun
ti pe Kashamu lẹjọ lori ẹsun ibanilorukọ jẹ. O ni ọpọ awọn to gbọ ẹsun to fi
kan oun ni wọn bẹrẹ si ni pe oun pe ki lo ṣẹlẹ pẹlu bi wọn ṣe sun mọ ara wọn
to, idahun to ni oun fun wọn ni pe ija lawọn ni kawọn pari ninu ẹgbẹ PDP ipinlẹ
Ogun, ki wọn ye gbe ara wọn lọ sile-ẹjọ mọ ni ko tẹẹ lọrun to parọ mọ oun pe
oun ti gbowo lọwọ Ladoo
Bayọ Dayọ tun sọ pe ‘’Gbogbo igba taa wa papọ naa pẹlu irọju
ni, nitori pe suuru ti agbalagba ni, ni
mo ni, ohun to fi n lọ mi, ki i ṣe nnkan ti wọn fi n lọ alaga ẹgbẹ.
“Mo ni ọpọlọpọ suuru pe bo ti wu ko ri, maa lo akoko mi
tan bi alaga ẹgbẹ.ki n si maa bọ nile ọdọ mi. Eyi ti wọn wa n sọ lakooko yii pe awọn kan fẹẹ
lọ ṣe jagidijagan latigba ọfiisi, ki lo kan mi, pẹlu ọjọ-ori mi pe wọn fẹ lọ da
wahala silẹ.
‘’Ko ti si latigba taa ti da ẹgbẹ PDP silẹ,ko si ẹnikẹni
to sọ pe oun ṣe alaga ẹgbẹ naa fọdun mẹjọ nipinlẹ Ogun ri, Buruji wa lara awọn
to jẹ ko ṣe e ṣe.Eeyan ko wa gbọdọ ṣe oore ko wa jokoo sidi ẹ.
O ni kii ṣe igba akọkọ ree toun ti gbe igbesẹ toun gbe
yii, o ni o ti le lọdun meji touni kọ lẹta lọ si Abuja, Ọnarebu Akitan
lo sin oun lọ nigba naa, toun alaga, akọwe ati oludamọran ẹgbẹ lapapọ sọrọ pe
ki wọn ba wọn gbe igbesẹ ki isọkan le wa ti gbogbo nnkan yoo fi lọ daradara.
O wa pari ọrọ ẹ pe pẹlu gbogbo nnkan to n ṣẹlẹ yii ko le
mu ifasẹyin ba oun lori irẹpọ toun n ṣe. Kaka ki oun pada, oun yoo tubọ tẹra mọ ọn ni. O si tun jẹ
koun fojoojumọ lero lẹyin.
No comments:
Post a Comment