Alaaji Hammed Abọdunrin ni ọga agba fajọ alaabo siifu nipinlẹ Ogun, o si jẹ ọkan lara awọn ti wọn ṣamojuto eto abo fun ti arun koronafairọọsi to ti tan kalẹ kaakiri orileede yii, ṣugbon ti wọn n gbogun ti nipinlẹ Ogun. Ọkunrin naa ti ba oniroyin wa sọrọ lori awọn iriri ẹ gẹgẹ bi alaabo ilu latigba ti konile-o-gbele ti bẹrẹ lati nnkan bi ọsẹ meje sẹyin,ohun to ba wa sọ niyii.
“ Nipa awọn iriri mi latigba ti konile-o-gbele ti bẹrẹ, ẹ
jẹ ki n kọkọ bẹrẹ lori konile-o-gbele, igba ti ofin yẹn kọkọ bẹrẹ, awọn eeyan
ipinlẹ Ogun, fọwọsowọpọ pẹlu awọn alaabo ilu. Awọn naa mọ riri wahala to n bẹ
ninu isunmọ-ra-ẹni.
Ṣugbọn iriri mi naa tun ni pe awọn kọlọransi kan tun wa,
ti wọn fi agidi jade bẹẹ ni wọn tun da oriṣiriṣi ọgbọn alukọrọmi pẹlu. Ijọba ti
ṣofin pe ẹni to ba gbe ounjẹ tabi nnkan ẹran ọṣin,wọn ko gbọdọ mu wọn.
A wa rii pe awọn eeyan wa dọgbọn lati lo anfaani nnkan wọnyii
lati maa fi dọgbọn jade. Lọrọ kan awọn Naijiria ṣetan lati fọwọsowọpọ lati
gbogun ti korona fairọọsi to tan kalẹ yii.
Nnkan to ṣẹlẹ yii tun fi ye wa pe ijọba tun ti jẹ ka mọ bi
a ṣe lagbara to,nipa ounjẹ boya a le bọ awọn eeyan wa to wa lorileede yii abi a
ko le bọ wọn.
Awọn eeyan ko tii jẹ onisuuru lati ma ṣe nnkan bo ṣe yẹ ki
wọn maa ṣe,ijọba ipinlẹ yii fawọn eeyan wa lanfani ọjọ kọọkan lati maa jade ra
ounjẹ fun bi wakati mẹjọ, ṣugbọn aini suuru si n jẹ kawọn eeyan jọ maa pejọ pọ.
Nile ifowopamọ, a ni awọn wahala lati jẹ kawọn eeyan maa to
lọwọọwọ, ki wọn si jinna si ara wọn, eleyii fi han wa pe a ti kọ ẹkọ, bi wọn ṣe
bọwọ fun ofin awọn nnkan to ba le jẹ akoba.
Iriri mi tun ni pe awọn amookunsika fẹẹ lo akoko konile-o-gbele
yẹn lati fi ja awọn adugbo ni ole, eleyii tun fi han wa pe iwa oju lalakan fi n
sọri wa ko tii muna doko to.
Ẹ o ri pe nigba tawọn eeyan naa bẹrẹ oju lalakan fi sọri
yii, o jẹ ki awọn iwa naa dinku. Awọn taa jẹ alaabo gan-an igbaradi pupọ ko
tete si, nitori aṣọ ẹgbẹjọda ti wọn gbe sọrun yẹn ati ibọn ti wọn n gbe dani ko
ran aisan yii. O yẹ ki imurasilẹ to peye wa fun wọn,kawọn naa maa wa nnkan ti wọn
yoo fi dabobo ara wọn.
Eleyii lo mu kawa lọ ṣe domu, awa si ni ẹni akọkọ ti yoo
kọkọ se funra wa.Ti a si tun lọ ṣe ifọwọ fawọn eeyan wa to n ṣiṣẹ, ki abo to peye le wa fun wọn lẹnu iṣẹ wọn.
Mo tun woye pe awa araalu ati agbofinro, agbọye ko tii wa
daadaa,nigba tawọn agbofinro ba sọ pe kawọn araalu ma ṣe nnkan, ṣugbọn ti wọn
ko nii gbọ laimọ pe wọn n gba oromọdiẹ wọn lọwọ iku.
Ko ti ye awọn eeyan daadaa pe ti araalu ni agbofinro n ṣe,
bo tilẹ jẹ pe awọn naa ni lati gbe gbohungbohun lọ si ọja, a gbe omi ti wọn fi
n fọwọ lọ si aarin ọja, a kọ wọn bi won yoo ṣe maa fọwọ wọn, pẹlu gbogbo eleyii
nnkan to ba tun fẹẹ kun diẹ kaato lọjọ iwaju, o dabi a ti kọ ẹkọ to maa ṣe wa
loore ati anfaani fun wa.
No comments:
Post a Comment