Ẹgbẹ apapọ awọn onigbagbọ CAN tipinlẹ Ogun pe fun ipade pẹlu ijọba - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Tuesday 26 May 2020

Ẹgbẹ apapọ awọn onigbagbọ CAN tipinlẹ Ogun pe fun ipade pẹlu ijọba




Ẹgbẹ apapọ awọn onigbagbọ CAN nipinlẹ Ogun  fẹẹ ki ipade kan waye laaarin awọn olori ẹlẹsin ati ijọba ipinlẹ naa lati le jọ forikori pọ lati mọ bi nnkan ṣe n lọ, ati lati jọ gbimọ pọ bi ilọsiwaju yoo  tun ṣe maa jọba, ki alaafia le tubọ wa nipinlẹ ọhun.

Ipe fun ipade yii waye ninu atẹjade kan ti wọn fi sita, eyi ti Biṣọọbu Tunde Akin-Akinsanya, to jẹ alaga ẹgbẹ naa nipinlẹ Ogun fọwọ si, nibẹ ni wọn tun ti ki Gomina Dapọ Abiọdun ku oriire ọdun kin-in-ni iṣejọba ẹ, ti yoo waye lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii, tii ṣe ọjọ kọkandinlọgbọn. Pẹlu ayẹyẹ ọjọọbi ọgọta ọdun to dele aye.

Ipade naa ti wọn pe akọle ẹ ni ipade lati tu ero ọkan sita ni wọn ti fẹẹ ki awọn olorin ẹlẹsin gbogbo yoo ti jokoo papọ pẹlu ijọba, ti wọn yoo si sọ ero ọkan onikaluku lọna ti yoo mu itẹsiwaju ba iṣejọba to n lọ lọwọ. Ati erongba lati jẹ kawọn ile ijọsin gbogbo ti wọn ti pa ko le di ṣiṣi lati le fadura koju arun korona fairọọsi
     .       
B lakan naa ni wọn tun lo anfaani ninu atẹjade wọn lati fi gboriyin fun Gomina Dapọ Abiọdin lori ilakaka ẹ lati gbogun ti arun korona fairọọsi, eyi to ti mu ki konile-o- gbele wa nipinlẹ ọhun lati bi ọsẹ meloo kan sẹyin.

Wọn ni bo tilẹ jẹ pe ipinlẹ Ogun naa wa lara awọn ibi afojusun fun arun korona fairọọsi naa nitori bi wọn ṣe mule ti ipinlẹ Eko,ti wọn ni kinni yii pọsi ṣugbọn wọn ni gbogbo agbara ati ọgbọn oun oye ti Gomina lo ko jẹ ki o nipa pupọ lara awọn olugbe ipinlẹ Ogun.

Bẹẹ ni apapọ awọn onigbagbọ tun wa dupẹ lori  ounjẹ ọfẹ tijọba ipinlẹ yii fawọn araalu lati fi le gbogun ti ebi lakooko ti konile-o-gbele yii n lọ lọwọ, wọn ni ijọba to fẹran awọn eeyan ẹ ti ko fẹ ki ebi pawọn eeyan ẹ ku ni ijọba Dapọ Abiọdun.

Alaga ẹgbẹ awọn onigbagbọ tun wa lo akoko yii lati bawọn ọmọde yọ fun ti ayajọ ajọdun ewe pẹlu adura pe gbogbo wọn ko ni rẹ danu, o tun wa ki gbogbo awọn musulumi ku ti itunu awẹ ti wọn ṣẹṣẹ pari yii

Wọn wa pari ọrọ wọn pe ẹgbẹ apapọ onigbagbọ nipinlẹ Ogun ko ni figba kankan rẹwẹsi nipa fifi adura ran ipinlẹ yii ati orileede lapapọ lọwọ lati mu wa bori arun korona fairọọsi.

Pẹlu idaniloju ati igbagbọ pe laipẹ yii ni imọlẹ yoo pada bẹrẹ si ni tan kaakiri, ti gbogbo nnkan yoo si pada bọ si, bo ṣe wa tẹlẹ.






No comments:

Post a Comment

Pages