Idunnu
lo subu layọ awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP, tipinlẹ Ogun, nigba ti mẹẹẹdọgbọn ninu
wọn tun gba mọto lọfẹẹ, eyi ti wọn ni ajọ ọmọ-ilu, iyẹn Ọmọ-Ilu Foundation, ti
Sẹnetọ Buruji Kashamu da silẹ, ṣagbatẹru ẹ.
Gẹgẹ
bi a ṣe gbọ, wọn ni wọn fawọn eeyan naa lẹbun ọhun lati fi ro wọn lagbara. Ninu
atẹjade ti wọn fi sita, eyi ti wọn pe akọle ẹ ni ‘’Ko si nnkan to le da wa
duro, a n sun siwaju’’ nibẹ naa ni wọn tun ti pin ọkada ọkada lawọn ijọba ibilẹ
kọọkan, eyi ti wọn lo ti bẹrẹ ni ijọba ibilẹ Ijẹbu-North ati Ọbafẹmi-Owode.
Bẹẹ ni wọn ni erongba
awọn ni lati pin igba le aadọta mọto, bẹẹ tun ni ẹkọ ọfẹ atawọn ironilagbara
mii in lo wa lọkan wọn lati ṣe fawọn ọmọ ẹgbẹ wọn.
A
o ranti pe laipẹ yii ni Sẹnetọ Kashamu fawọn oloye ẹgbẹ tuntun PDP ni mọto pẹlu
ileri pe awọn nnkan mii in tun bọ toun
fẹẹ ṣe.
No comments:
Post a Comment