Ṣẹnetọ Buruji Kashamu ti sọ pe bi
igba teeyan ko ba mọ nnkan to n sọ mọ ni ọrọ ti alaga ẹgbẹ oṣelu PDP lapapọ,
Ọmọọbọ Uche Secondus, sọ ninu iwe iroyin oloyinbo kan, nibi to ti sọ pe oun ki I
sọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP, pe awọn ti le oun danu, o ni ọrọ ologogoro lọrọ naa,
nitori titi di akoko yii ojulowo ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP loun.
Ninu atẹjade ti ọkunrin naa fi sita
lo ti sọ pe oun fẹ ki alaga ẹgbẹ naa lapapọ mọ pe ẹgbẹ lati apapọ de ipinlẹ
tabi ibilẹ ki I ṣe tẹnikan tabi ogun ẹnikẹni, bi ko ṣe agbajọpọ eeyan.
O ni loootọ ni Secondus jẹ alaga ẹgbẹ naa lapapọ ṣugbọn iyẹn
ko ni jẹ oludasilẹ to le ma sọ pe ẹnikan ni lo jẹ ojulowo ọmọ ẹgbẹ tabi ki i ṣe
ọmọ ẹgbẹ, o ni ko gba ẹnu ẹ rara.
Kashamu ni gẹgẹ
bi ipo alaga naa, o yẹ ko jẹ baba fun gbogbo wọn, ti ko yẹ ko maa gbe lẹyin
ẹnikan, Ati pe oun ki i ṣe awọn kan to fẹgbẹ naa silẹ lọ kọwe adehun pẹlu ẹgbẹ
oṣelu Allied Peoples Movement (APM) ninu
ibo to waye nipinlẹ Ogun lọdun 2019.
O ni lori lile ti alaga ẹgbẹ naa lapapọ
sọ pe wọn le oun nini ẹgbẹ, o mu wa si iranti pe ko lọ wo iwe akọsilẹ yoo ri pe lọdun 2019 lakooko ti ibo gbogbo
gboo fẹẹ waye ni ileejọ giga ti wọgile bi wọn ṣe ni wọn le oun dani. Ọjọ kẹwaa,
oṣu kẹwaa, 2018, lo ni idajọ naa waye. O ni wọn sọ pe bi wọn ṣe le oun danu ko
lẹsẹ nilẹ rara.
Ẹni to ti figba
kan jẹ aṣoju wọn nile igbimọ aṣofin fun ẹkun Ogun West tun ṣalaye pe lara awọn
mẹrin tileeejọ da lare nigba naa ni alaga ẹgbẹ naa nipinlẹ Ogun, Bayọ Dayọ, to
ti wa pẹlu wọn bayii.
O ni aṣẹ ile-ẹjọ naa si wa, ti wọn
ko si le yipada ayafi ti wọn ba fẹẹ gbena woju ofin O ni oun gan-an lo foun lanfaani
lati gbe apoti gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu ọhun lọdun 2019.
O ni fun idi eyi gẹgẹ bi igbimọ oloye
ẹgbẹ naa lapapọ tẹlẹ ati ojulowo ọmọ ẹgbẹ naa nipinlẹ Ogun,ọmọ ẹgbẹ si ni oun
titi di akoko yii, ko si si nnkan to le yẹ.
Buruji ni boya alaga ẹgbẹ naa lapapọ
ti gbagbe nitori awọn iṣẹ ẹgbẹ to wa niwaju ẹ pe wọn ti wọgile lile ti wọn le
oun danu ati pe o yẹ ko fi ẹmi imoore ẹ han lori ipa tawọn ẹgbẹ naa n ko
nipinlẹ Ogun.
O ni lori ipade
gbogbogboo ẹgbẹ naa ti wọn ṣe nipinlẹ Ogun ti Secondus sọ pe ko lẹsẹ nilẹ, o ni
ẹnikẹni to ba tapa si yoo foju winna ofin, o ni ti ko ba le ṣe bi baba lati
yanju wahala to ba wa nilẹ, amọran oun ni ko jẹ ki ofin ko ṣiṣẹ ẹ.
No comments:
Post a Comment