Lojumọ to mọ lonii, ti wọn ba darukọ oṣere tiata Yoruba ti ede ati aṣa da lẹnu ẹ, wọn ko ni darukọ meji rara ti wọn yoo fi darukọ Adedeji Aderẹmi, tọpọ awọn eeyan mọ si Ọlọfaana.
O fẹẹ jẹ pe ko si ninu awọn ere to kopa ninu ẹ yala
redio, tẹlifiṣan ati fiimu ti ọkunrin naa ba ti kopa tawọn eeyan kii woo ni
iyalẹnu nigba ti awọn ede Yoruba naa ba n bọ lẹnu ẹ.
Ibeeere tawọn eeyan si maa n beeere lọwọ ara wọn ni pe
nibo ni ọkunrin to tun jẹ ọkan lara awọn oloye Ẹdẹ, nipinlẹ Ọṣun, ti maa n
rawọn a-gbọ- ya nilẹnu ede naa.
Ipa ti ọkunrin naa ti ko ninu iṣẹ tiata ki i ṣe kekere, ọpọ
awọn itan loriṣiriṣi ni ọkunrin yii ti ṣe tabi kopa ninu ẹ, Awọn ere bii Baṣọrun
Ogunmọla,Balogun Ibikunle,Ogedengbe agbogungboro ati bẹẹbẹẹ lọ
Bẹẹ ni Ọlọfaana atawọn ẹgbẹ oṣere ẹ ti ṣe awọn ere ọlọsẹ
mẹtala bii Ọdẹtẹdo, Lakaaye, atawọn ere miin fun ileeṣẹ tẹlifisan TSOS to ti di
BCOS.
A ko le ma mẹnuba awọn oṣeere to tipa agba oṣere yii goke
tawọn eeyan fi mọ wọn, awọn bi Gbọlagade Akinpẹlu tọpọ mọ si Ogunmajek, Musilu
Dasọfunjo tọpọ mọ si Esu, Ariyọ Minkalu, Alaaji Kareem Ọlatinwọ tọpọ mọ si
Tọwọndun, Fẹsọ Oyewọle atawọn mii in.
Ipa to ko nidii
iṣẹ yii ko lafiwe, to si ti fipa bẹẹ rin irinajo kaakiri oke-okun. Idi niyii
tọpọ awọn eeyan fi n ki Oloye Deji Aderẹmi ku ayẹyẹ ọjọọbi aadọrin ọdun to pe lonii.
No comments:
Post a Comment