Bo tilẹ jẹ pe ero
ọkan awọn araalu nipinlẹ Ogun, ni pe boya Gomina Dapọ Abiodun, yoo gbẹsẹ kuro
lori ofin konile-o-gbele, eyi ti wọn ti wa lẹnu ẹ lati nnkan bi ọsẹ marun-un
sẹyin, ṣugbọn biri lọro yii nigba ti Gomina sọ pe pẹlu akọsilẹ to ṣi wa nilẹ
lori arun koronafairọọsi, o di dandan ki awọn araalu tẹsiwaju igbele wọn fun ọsẹ
kan.
Gẹgẹ bi ipade
to bawọn oniroyin ṣe ni alẹ ana, ni ọfiisi gomina to wa niluu Abẹokuta, O sọ pe
afikun ọsẹ kan yii ṣe pataki nitori erongba awọn araalu ti wọn ṣe lati le sọ
nipa bi wọn ṣe ri korona fairọọsi yii ati igbesẹ wo lo tun kan.
O ni erongba ọpọ
awọn eeyan lori ẹrọ alatagba twiita lo ti ni ninu ẹgbẹrun mẹfa awọn eeyan to da
si ida mẹtalelaadọta lo fọwọsi ki igbele tẹsiwaju, nigba ti ida mẹtalelogoji
fẹẹ ki wọn ṣagbeyẹwo nigba ti ida mẹrin ko sọ pato.
Dapọ Abiọdun
tun ṣalaye pe pẹlu awọn ẹri tawọn ti ni nilẹ yii, ati bawọn araalu ko ṣe
fọwọsowọpọ pẹlu ilana ati eto ilana ti wọn la silẹ lori koroona fairọọsi yii, kawọn
araalu pada so konile- o- gbele wọn titi di ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹrilelogun,
oṣu karun-un, ọdun yii.
O
ni’ A ṣetan lati tẹsiwaju lati maa mọ bi nnkan ṣe n lọ lakooko konile-o-gbele
lawọn agbegbe wa, pẹlu idaniloju pe abayọri yoo de ba arun ọhun, ti opin yoo si
de ba jijoko tawọn eeyan jokoo nile’
‘’Mo
tun fẹẹ mu wa fun iranti yin pe iṣede ti aarẹ orileede yii ṣofin ẹ si n
tẹsiwaju laaarin aago mẹjọ alẹ si aago mẹfa aarọ kutu ṣi wa nilẹ ati pe fifinde
irinajo lati ipinlẹ kan lọ si keji naa n lọ’
O ni ko si aye fawọn
ọmọ ipinlẹ Ogun atawọn ti wọn ki i ṣe ọmọ ipinlẹ ọhun fi tipa wọlu, ẹnikẹni ti
ọwọ ba tẹ lo sọ pe yoo jẹ iyan ẹ niṣu. O tun wa mu fun iranti pe ijọba yoo
tẹsiwaju lati maa ṣe awọn nnkan to tọ, to si yẹ fawọn eeyan ẹ. O ni gbogbo
araalu lo ni lati fọwọsowọpọ pẹlu ijọba lati le koronafairọọsi kuro nipinlẹ naa.
No comments:
Post a Comment