Gbajumọ olorin
ẹmi nni, Adekunle Adeṣina Adeokun ti fidi ẹ mulẹ pe Ọlọrun lo sọ foun pe koun
maa kọrin ẹmi bẹẹ lo ko tun gbọdọ maa ṣe ere itage to ba jẹ ti aye mọ, nitori iṣẹ ipe toun gba a ni.
Ọkunrin yii
sọrọ ọhun lakooko to n ba oniroyin wa sọrọ nipa bo ṣe di ilu mọn-ọn-ka olorin
ẹmi atawọn nnkan to fi foju la kọja latigba to ti bẹrẹ titi di akoko yii.
Wolii Adekunle
sọ pe ‘’Lati kekere ni mo ti darapọ mọ ẹgbẹ
akọrin ni ijọ Kerubu ati Serafu New Eden, niluu Ibadan. Nibẹ ni mo ti kọkọ ṣawari
ẹbun orin ti Ọlọrun fun mi”
Olorin ẹmi naa
tun fi kun ọrọ ẹ pe oun ti figba kan ṣe tiata ni kekere tawọn si da ẹgbẹ oṣere
ti wọn silẹ pẹlu ọrẹ ẹ kan Johnson Akinpelu,
o ni awọn ni ẹgbẹ alawada kan ti wọn Bọmọde-o-ku Jesters,
O ni ‘Oteku ni orukọ ere ti wọn maa
n pe mi nigba naa, nigba ti ọrẹ mi yẹn si n jẹ Jonto. Ọpọ idojukb ni mo ri nigba
naa latọdọ iya to bi mi lọmọm nitori wọn ko fẹẹ ki n ṣere tiata.
O ni eyi lo fa a
toun fi gbajumọ iṣẹ orin kikọ. Ile igbafẹ lo
ni oun ti n kọrin tẹlẹ, toun si ni awọn ọmọ ẹyin, gẹgẹ bi olorin juju. Iran lo
sọ pe o jade si oun pe Ọlọrun ko fẹẹ koun
maa kọrin aye bi ko se orin ẹmi.
Nigba to n sọ nipa awokọṣe ẹ nidii
iṣẹ orin ẹmi, o ni ‘Awọn ti mo maa n wo bi
awokọṣe gẹgeẹ bi agba olorin nigba naa, awọn meji ni, ti mo si fẹ lati ma gbọ orin
wọn daadaa. Ajihunrere Akin Adebayọ ti gbogbo eeyan mọ si Imọle Ayọ ati Pasitọ J.K Adelakun,
Ayẹwa International, Amọna Tete ma bọ
Adeokun tun sọ
pe rẹkọọdun orin ẹmi toun ti ṣe ti to mẹsan-an. Ati pe ọdun 1996, loun ti bẹrẹ si nii gbe e jade, akọle ẹ ni Moji ire,
o ni eyi to gbilẹ ju tawọn eeyan maa fi n pe oun to sọ makẹẹta oun di olowo ni
77 everlasting prayer song toun ṣe ninu oṣu kejila ọdum 2010.
Bẹẹ lo tun sọ pe “Ọpọ ipenija ni mo ti
ba pade nidii iṣẹ orin, ṣugbọn a dupẹ lọwọ Ọlọrun lonii. Mo fẹran orin ju iṣẹ
ere itage lọ’’
Adekunle tun
sọ pe ọjọ tinu oun dun ju lọjọ toun bi ọmọ oun akọbi, pe oun naa di di
baba aburo. Ati pe ọjọ to ba oun ninu jẹ
lọjọ ti iyawo oun fi oun silẹ tawọn ẹbi ẹ ni ko gbọdọ fẹ oun mọ.
O wa pari ọrọ
ẹ pe ‘Mo ni iṣẹ iranṣẹ mi gẹgẹ bi woli, ko
di iṣẹ orin ati iṣẹ ere itage mi lọwọ nitori mo ti gbe iṣẹ ere itage pada wa
si ti kristẹẹni. Nipa ti orin, Ọlọrun si n tẹ siwaju nitori mo n ṣe rẹkọọdu kan lọwọ bayii pẹlu ajọṣepọ pẹlu awọn olorin musulumi, Ọmọ
imaamu to fẹ fẹ Ọmọ Rẹfurẹdi lakọọle ẹ,covid-19 lo n da wa duro.
|
No comments:
Post a Comment