Gẹgẹ bi atẹjade to jade lati ọfiisi
iroyin Aṣofin naa, lo ti sọ di mi mọ pe lori ọna lati fopin si ebi lakooko idaamu
koronafairọọs nipinlẹ Ogun, awọn ounjẹ bii apo gari onikilo mẹwaa, apo irẹsi
toun naa jẹ kilo mẹwaa, pali indomiini ni wọn fẹẹ pin fawọn ẹgbẹrun meji mọlẹbi
ni ẹkun Ogun West.
Tolu Ọdẹbiyi tun sakiyesi pe pẹlu
iwoye bi arun koronafairọọs naa ti n ṣe n tan kaakiri orileede yii, to mu ki
ofin konile-o-gbele ati iṣede waye, oun yoo ri pe oun ṣakitiyan lati maa pese
ounjẹ loorekoore fawọn eeyan ẹ, ki wọn fi le koju ipenija ti wọn ba n ba pade
lakooko taa wa yii.
O tun wa lo akoko naa lati fi ẹmi
imoore ẹ han si Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun, MFR atawọn eeyan
igbimọ ẹ lori bi wọn ṣe fọwọsowọpọ lati
gbogun ti korona fairọọs, to mu aifọkanbalẹ wa lati bi oṣu meloo sẹyin.
Bẹẹ lo tun rọ awọn eeyan agbegba ẹ ati ipinlẹ Ogun lapapọ
lati ri pe wọn pa awọn ofin ti wọn la silẹ fun wọn mọ, ki wọn si sọra fun
ifara-kan-ẹni, pẹlu adura pe ki Ọlọrun pa gbogbo wa mọ, ki a le bori arun yii.
No comments:
Post a Comment