Adeleke Adekọya, ẹni ti wọn ṣẹṣẹ yan gẹgẹ bi ọba tuntun
ni Oke-Agbo, ni Ijẹbu Igbo, ti ṣedaro agba, akọni oniroyin nni, Ọgbeni Ayọmide
Giwa, tọpọ mọ si Ay, to jade laye ni alẹ ọjọ Aiku, Sannde, ana.
Gẹgẹ bo ṣe wi, o ni bi ala lọrọ naa jẹ foun nigba ti wọn
ni akọwe iroyin Gomina tẹlẹ nipinlẹ Ogun, Ọtunba Gbenga Daniel ku, titi di
akoko yii lo ni jinnijinni ẹ si mu oun, toun si n beeere lọwọ ara oun pe ṣe
beeyan ṣe n ku ree.
O sọ pe adanu nla ni iku ọhun jẹ fun gbogbo ọmọ Ijẹbu-Igbo
paapaa julọ Oke- Agbo nitori Ayọ Giwa jẹ akinkanju eeyan ti ki i ṣe imẹlẹ lori
gbogbo nnkan to ba n ṣe.
Ọmọọba Adeleke tun ṣalaye pe ko ti i pẹ tawọn sọrọ nipa ibi
ti nnkan de lori ọrọ oye ọba ti wọn yan oun yii, koda ka ni ti ki i ba ṣe ti
koronafairọọs ni, wọn ko ba tu mu ọjọ oye.
O ni gbogbo igba ti wọn fi fẹẹ yan oun ni Ayọ Giwa fi wa
lẹyin oun, awọn oniroyin to wa sibẹ lọjọ naa, ipasẹ ẹ ni. O ni ki i ṣe iru
akoko yii lo wa yẹ ki iku gba Ayọ Giwa lọwọ awọn
Bẹẹ lo tun sọ pe Ayọ tun jẹ ẹni to maa n fojoojumọ wa
igbega ati ilọsiwaju ilu Oke-Agbo, o wa gbadura pe ki Ọlọrun tu awọn ẹbi ẹ ninu, ki aye to fi silẹ ko ma ṣe ṣofo.
Ni nnkan bi aago mẹwaa alẹ ana lokiki gba gbogbo ilu Ijẹbu-Igbo
pe agba oniroyin naa jade laye, ohun taa gbọ ni pe ko si nnkan to ṣe e tẹlẹ, awọn
kan si sọ pe gbogbo irọlẹ ana, awọn jọ n ṣere, ko to di pe aisan naa ki i mọlẹ
ni nnkan bi aago mẹfa abẹ irọlẹ, to si gba ẹmi ẹ lọ.
A gbọ pe wọn ti sin Ayọ Giwa niluu won ni Oke-Agbo, Ijẹbu
Igbo. Ki Ọlọrun fọrun kẹ wọn.
No comments:
Post a Comment