Ẹgbẹ oṣelu PDP tipinlẹ Ogun ti yan Samson Bamgboṣe gẹgẹ
bi alaga fẹgbẹ tuntun fẹgbẹ wọn, ọkunrin naa si tiṣeleri pe gbogbo agbara loun
yoo sa lati ri pe ijọba bọ mọ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, (APC) lọwọ iyẹn lọdun 2023.
Ọkunrin naa sọrọ yii
lakooko to n bawọn oniroyin sọrọ niluu Abẹokuta, o sọ pẹlu idaniloju pe oun
atawọn oloye oun yooku yoo ṣiṣẹ pọ pẹlu iṣọkan lati rii pe PDP jawe olubori
ninu ibo gbogbogboo nipinlẹ Ogun.
Bamgboṣe ni wọn ṣe
ibura fun pẹlu awọn oloye tuntun ti wọn yoo ba ṣiṣẹ pọ, awọn naa ni Kẹhinde Ọladẹhinde
to jẹ igbakeji alaga, Adeleke Shittu, oun ni akọwe nigba ti Abimbọla Lanre si
jẹ olori awọn obinrin.
Rafael Olaosebika ni
olori awọn ọdọ, Ọlasunkanmi Oyejide ni
akọwe olupolongo, Vivian Ogunwo ni olubanidamọran nipa ti ofin, Tomi Anifowose
akọwe owo nigba ti Toyin Atọba jẹ akapo.
Bakan naa ni idunuu
tun subu layọ awọn oloye ẹgbẹ naa tuntun nigba ti ajọ Ọmọ Ilu iyẹn “Omo-Ilu
Foundation”, eyi ti Sẹnetọ Buruji Kashamu da silẹ fun wọn ni mọto tuntun kọọkan lati le jẹ moriya fun wọn.
Bamgboṣe to ti figba kan jẹ igbakeji alaga ẹgbẹ naa
tẹlẹ tun sọ siwsju pe lara erongba oun ni pe ki gbogbo ẹgbẹ wa ni isọkan, ki
wọn si pada sinu ogo ti wọn ti wa tẹlẹ.
O ni ko sẹni ti ko mọ
pe PDP lo n sakoso ipinlẹ yii nigba kan, ko to di pe wahala ṣẹlẹ laarin ọna,
ṣugbọn ni bayii awọn ti ṣetan lati mu wahala naa kuro kawọn si pada sinu ogo to
ti sa lọ tẹlẹ ninu ẹgbẹ ọhun.
O wa ni iṣẹ akọkọ to
wa niwaju oun bayii ni lati ri pe gbogbo awọn to ti sako lọ ni lati pada wa ki
wọn jọ ṣejọba lati fi mu ẹni to ba kun oju osuwọn lati dije fun ipo gomina,
ninu ibo ọdun 2023.
Lori
boya ofin kin yiyan oloye tuntun ti wọn yan lẹyin, alaga tuntun naa sọ pe awọn ọmọ
ẹgbẹ ti wọn yan awọn oloye ba liana ofin ẹgbẹ naa mu. O ni yiyan awọn oloye ti
bẹrẹ lati wọọdi si ijọba ibilẹ, ati ẹlẹkunjẹkun iyẹn Senetorial..
No comments:
Post a Comment