Lati le gbogun ti iwa isunmọ-ra-ẹni lawujọ nitori arun korona fairọọs to gbode, ajọ alaabo ilu siifu tipinlẹ Ogun ti bẹrẹ igbesẹ lati dena iru nnkan wọnyii.
Gẹgẹ
bi atẹjade ti ọga agba ajọ naa, Alaaji Hameed Abodunrin fi sita, lo ti sọ pe
awọn ọmọọṣẹ ẹ ti bẹrẹ si ni lọ kaakiri paapaa awọn banki tiru nnkan bẹẹ ti maa
n waye lati ri pe awọn eetan n fi alafo silẹ fun ara wọn gẹgẹ bi ofin ṣe laa
kalẹ.
Atẹjade ọhun eyi ti
Dyke Ogbonnaya, to jẹ agbẹnusọ fajọ naa fi sita lorukọ ọga agba wọnyii lo ti pasẹ pe igbesẹ jinjinna sira ẹni yii jẹ
eyi to ṣe pataki lati le fi tete dena arun to n tan kalẹ ọhun.
O wa paṣẹ fawọn ẹka to
n ri ijamba pajawiri labẹ ajọ naa lati ri pe wọn wa fa awọn ila ti yoo faye
jijina sira ẹni silẹ lawọn banki pẹlu aṣẹ lọdọ ijọba
Bakan naa ẹwẹ,
Abọdunrin tun ti bẹbẹ fun ẹrọ ti wọn fi dena arun korona, ti yoo maa fin
kaakiri inu ọgba, o ni eleyii ṣe pataki nitori ọpọ ileeṣẹ to wa labẹ oun ni wọn
n mu awọn ọdaran bii awọn to n ji epo wa, atawọn oniṣẹ ibi mii in, ki wọn ma ba
tipasẹ ẹ ko arun yii..
O ni bi ọga agba yii
ṣe n bẹbẹ fun ẹrọ yii bẹẹ lo tun ke si ileeṣẹ to n ri si ọrọ ayika lati pese
awọn kẹmika ti wọn le lo lakooko.
|
No comments:
Post a Comment