Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun, tun ti ṣafikun konile-o-gbele
to n lọ lọwọ nipinlẹ naa pẹlu osẹ kan lati le jẹ ki adinku ba arun korona fairọọs
to n tan kaakiri.
O sọrọ yii lakooko to n bawọn oniroyin sọrọ nirọlẹ ọjọ Ẹti,
Furaide, ni ọfiisi gomina to wa niluu Abẹokuta.O
sọ pe ẹdun ọkan lo n jẹ fun ijọba lori bi abajade awọn to ti lugbadi arun naa ṣe
n pọ si nipinlẹ yii.
Abiọdun sọ pe iye to jẹ pe ko to nnkan tẹlẹ ti wa di
nnkan topọ pẹlu bi konile-o-gbele ṣe wa, ti isinmi ranpẹ si n wa pẹlu. O ni
laaarin ọsẹ kan iye awọn ti wọn sọ pe wọn ni arun naa titi di ọjọ keje, oṣu yii
ti jẹ ọgọrun-un.
Awọn ogun lo sọ pe wọn ti ni alaafia, ti wọn ti da wọn
pada sọdọ awọn ẹbi wọn, nigba tawọn meji pere si ti jẹ Ọlọrun ni pe. Eyi to jẹ
pe mejidinlọgọrin lo si wa ti wọn tọju lọwọ. O ni igbagbọ awọn ni pe awọn eeyan
naa yoo lọ sile ni alaafia.
Dapọ Abiọdun tun sọ pe ‘’ A o tẹsiwaju lati ri pe awọn ayẹwo
wa taa n ṣe yoo tun gbooro si, nitori bi mo ṣe n sọrọ yii, o ti le ni ẹgbẹrun mẹwaa
taa ti ṣe ayẹwo fun, bẹẹ lo jẹ ẹẹdẹgbẹta la ti ṣee fun lori ti arun korona’’
O ni gbogbo igbiyanju wọn lati ri pe gbogbo awọn to ba
kaasa arun yii ni itọju yoo bẹrẹ fun un loju ẹsẹ, nitori ko ma ba tan de awọn igberiko
Abiọdun ni ‘’ Ẹyin eeyan mi nipinlẹ Ogun, ẹ ko yan mi
lati maa ṣe ipinnu tabi ipinnu to ma lagbara, ṣugbọn lakooko yii a gbọdọ gbe awọn
igbesẹ to lagbara lati fi le du ẹmi awọn eeyan, nitori idi eyi la ṣe gbero lati
safikun konile-o-gbele gẹgẹ bi a ṣe n ṣe lọ tẹlẹ’’.
O ni lati ọla ọjọ Abamẹta, ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ Iṣẹgun
Tusidee, ati Ọjọbọ, Tọsidee ni konigbele yoo fi waye nigba ti isinmi yoo wa lọjọ
Aje, Monde, ọjọruu, Wẹsidee ati ọjọ Ẹti, Furaidee.
Bẹẹ lo ni iṣede
aago mẹjọ alẹ si n tẹ siwaju.
|
|||||
|
|||||
No comments:
Post a Comment