Ọnarebu Lanre Ẹdun, to n ṣoju ẹkun agbegbe Abẹokuta
South, nile igbimọ aṣoju-sofin niluu Abuja, tun ṣe bẹbẹ lonii, ọjọ Ẹti,
Furaide, nigba to fi ẹbun ounjẹ ranṣẹ sẹgbẹ awọn sọrọsọrọ ati aṣoju-kọroyin
nipinlẹ Ogun.
Ounjẹ naa lo fi ransẹ gẹgẹ bi iranwọ ounjẹ ọfẹ to n ṣe
kaakiri fun ti konile-o-gbele to n lọ lọwọ. Aṣaaju awọn obinrin ni wọọdu
kẹsan-an labẹ ẹgbẹ oṣelu APC, nipinlẹ Ogun, Arabinrin Adebọla Sunday lo ṣaaju
awọn ikọ Ọnarebu Lanre Ẹdun nigba ti Ọnarebu Mufutau Babatunde,Ọnarebu
Tunji Oloyede, Ọnarebu Moruf Kaka,
Michal Ogunfidodo ati Damilọla
Adewuyi tẹle.
Awọn ẹbun ounjẹ ti wọn
fẹgbẹ awọn sọrọsọrọ naa ni apo irẹsi kan, apo ẹwa kan ati apo gaari kan
irufẹ bẹẹ naa ni wọn ṣe fawọn aṣoju-kọroyin.
Nigba to n dupẹ lorukọ ẹgbẹ awọn sọrọsọrọ iyẹn FIBAN,
alaga ẹgbẹ naa, Ọgbẹni Fẹmi Omilani, dupẹ lọwọ Onarebu Lanre Ẹdun fun bo ṣe fẹbun
naa ranṣẹ si wọn.
O ni latigba ti konile-o-gbele naa ti bẹrẹ lawọn ọmọ ẹgbẹ
ko ti sinmi nipa ipolongo igbogunti arun korona fairọọs ọhun, ti wọn si maa n
la awọn eeyan lọyẹ.
O ni nnkan iwuri ni Ọnarebu naa ṣe, o wa rọ awọn oloṣelu
yooku lati fi tiẹ ṣe awokọṣe lati fi le ṣe koriya fawọn ọmọ ẹgbẹ FIBAN.
Bakan naa ni Ọgbẹni Johnson Onifade naa fi ẹmi imoore wọn
han si Ọnarebu Lanre Ẹdun, o dupẹ yii lorukọ Ọgbẹni Wale Adewumi, alaga ẹgbẹ awọn
aṣoju-kọroyin.
No comments:
Post a Comment