Awọn ara agbegbe Abẹokuta South ti Ọnarebu Lanre Ẹdun ṣoju fun nile igbimọ aṣoju-ṣofin, to wa niluu Abuja, ti dupẹ lọwọ aṣoju wọn lori bi ko ṣe jẹ ki ebi pawọn latigba ti konile-o-gbele ti bẹrẹ, fun ti arun koronafairọọs.
·
Idupẹ
yii waye lakooko ti Onarebu naa tun fawọn eeyan ẹ ni ẹbun ounjẹ loriṣiriṣ, bii
irẹsi, gaari, iṣu,ororo, epo pupa atawọn nnkan mii in, ninu eyi tọpọ awọn eeyan
agbegbe naa lọkunrin ati lobnrin ti jẹ anfaani ẹ.
·
Ninu ọrọ ti aṣaaju awọn obinrin ni wọọdu kẹsan-an labẹ ẹgbẹ oṣelu APC, nipinlẹ Ogun, Arabinrin Adebọla Sunday ka lorukọ Ọnarebu Lanre Ẹdun lo ti rọ awọn eeyan ẹ yii lati ri pe wọn pa gbogbo ofin to rọ mọ arun koronnfairọọs naa, nitori alaafia gbogbo wọn lo ṣe pataki soun.
O ran wọn leti pe idaboobo arun yii lo ṣe Pataki ti gbogbo
eeyan si gbọdọ maa wa ọna lati gbogun ti, nitori ko ma ba ran mọ wọn, nitori ẹ
lo ṣe ni ipolongo ati ilanilọyẹ ṣe n waye looorekoore fawọn araalu lati para
wọn mọ lori arun yii.
Bẹẹ ni Ọnarebu Ẹdun tun dupẹ lọwọ
awọn ẹlẹyinju aanu ti wọn ti dide iranlọwọ sawọn eeyan latigba ti konile-o-
gbele ti bẹrẹ , o tun wa ke si awọn ti Ọlọrun ba ṣẹgi ọla fun lawujọ lati ṣe
bẹẹ gẹlẹ.
Pẹlu adura pe
laipẹ yii ni arun naa yoo kasẹ nilẹ patapata lorileede yii.
|
No comments:
Post a Comment