Kofoworọla ti sọ pe emi kọ ni Ifẹoluwa to gun iya ẹ pa o - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Monday 4 May 2020

Kofoworọla ti sọ pe emi kọ ni Ifẹoluwa to gun iya ẹ pa o


Arabinrin Kofoworola Ẹlẹṣọ Taiwo, ti pariwo sita pe fọtọ oun ti wọn gbe sita pe oun pa iya oun, jẹ ibanujẹ ọkan foun, nitori pe oun kọ ni Ifẹoluwa Fẹyintọla to ṣiṣẹ naa, bi wọn ṣi ṣe lo fọto oun ya oun lẹnu pupọ.

 Ninu ọrọ ti Arabinrin naa ba wa sọ lori foonu laaarọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, lo ti sọ pe oun ko gbe ni Ẹdẹ, Ebute, Apapa niluu Eko loun gbe ati pe ko si wahala kankan laaarin oun ati ọkọ oun.

Obinrin ọhun tun fi kun un pe iya to bi oun ki i ṣe oniṣekuṣe, bẹẹ lo wa laye, to si wa laaye, bi wọn ṣe wa lo fọto oun si nnkan toun ko mọ nipa ẹ jẹ ibanilorukọ jẹ.


Nigba taa beeere lọwọ ẹ pe nibo ni wọn wa ti ri fọto ẹ yii, obinrin naa sọ pe oun ko le sọ pato, oun ko si fura si ẹnikẹni, ṣugbọn  nnkan to ba oun bayii ni pe kawọn ọmọ Naijiria mọ pe fọto oun ti wọn gbe sita kọ lẹni to pa iya ẹ.

A o ranti pe lọjọ Aiku, Sannde, niroyin kan jade pe Ifẹoluwa gun iya ẹ pa ni Owode- Ẹdẹ, nipinlẹ Ọṣun, nitori o ka mọ ibi ti ọkọ ẹ ti n ba  iya naa sun.


No comments:

Post a Comment

Pages