Olu-Itori gboriyin fun Dapọ Abiọdun lori igbogun ti arun korona fairọọs nipinlẹ Ogun. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Monday 4 May 2020

Olu-Itori gboriyin fun Dapọ Abiọdun lori igbogun ti arun korona fairọọs nipinlẹ Ogun.


Ọba Fatai Akorede Akamọ, Olu tiluu Itori tilẹ Ẹgba, ti gboriyin fun Gomina Dapọ Abiọdun, tipinlẹ Ogun lori akitiyan ẹ lati gbogun ti arun korona fairọọs latigba to n ti n gbilẹ. O ni iṣẹ kekere kọ ni Gomina naa ti ṣe paapaa julọ nipa awọn ẹbun ounjẹ tijọba fawọn to ku diẹ kaato lawujọ.


Kabiyesi sọrọ yii lakooko to n ba oniroyin wa sọrọ lori akitiyan ẹ lati gbogun ti arun naa lawọn agbegbe to jẹba le lori ati bo ṣe fawọn to ku diẹ kaato lẹbun ounjẹ, ki wọn ba le gbogun ti ebi, nitori ti ebi ba kuro ninu iṣẹ, iṣẹ ti buse.

O ṣalaye pe awọn dupẹ lọwọ Ọlọrun nitori pe latigba ti konile-o-gbele naa ti bẹrẹ lati nnkan bi ọsẹ mẹrin sẹyin lawọn eeyan ilu Itori ati agbegbe ẹ ti pa ofin mọ, tin wọn ko kuro nile wọn ayafi igba ti wọn ba fin wọn nisinmi lati jade.

O ni gbogbo nnkan tijọba ba ti sọ fun wọn n i wọn maa n ṣe, nitori wọn maa n gbọran,O ni wọn ni ki wọn maa fọwọ wọn, wọn ṣe bẹẹ, o ni ki wọn ma bo imu wọn, o ni wọn ko lodi sii pẹlu.

Olu –Itori sọ pe eyi to kan le nibẹ ni ebi, ṣugbọn awọn dupẹ lọwọ Ọlọrun pe o n ṣe iyanu ẹ. O ni gbogbo nnkan to ṣẹlẹ yii Ọlọrun mọ nipa ẹ, amọ awọn eeyan wa ko murasilẹ dee.


 O ni ijọba ṣe iwọn ti wọn le ṣe, ṣugbọn won ko le ṣe gbogbo ẹ, nitori naa lo ṣe lo akoko ọhun lati fi kesi gbogbo awọn ti Ọloọrun ba bunkun lawujọ lati dide iranlọwọ.

Oba Itori ni ẹda gbinyanju ni Ọlọrun nikan lo fere si, o ni loootọ ni korona naa n ṣẹlẹ ṣugbọn pẹlu igbagbọ o da oun loju pe Ọlọrun yoo mu kuro nilẹ yii lagbara Ọlọrun. O ni bi a ba ti ṣe nnkan to yẹ ka ṣe, arun naa ko ni de ọdọ wa.

Lori awọn ẹbun ounjẹ ti wọn fawọn eeyan lọfẹẹ niluu naa, O ni awọn dupẹ nitori awọn ounjẹ tawọn ti pin ti le ni ẹgbẹrun meji iẹsi ati gaari. O ni igba kọkanla ree tawọn yoo ṣe, ṣugbọn eyi to lagbara ju ni ti burẹdi nla ẹgbẹrun kan ati ẹja mẹẹẹdọgbọn tawọn fawọn fẹnikọọkan araalu.

O lawọn se eyi lati le jẹ kawọn araalu ri nnkan maa jẹ,ki wọn le pa ofin ijọba mọ.bẹẹ lo ni awọn fawọn to ku diẹ kaato lawujọ lowo. O loun ko ka si nitori Bibeli sọ pe ẹni to ba fun ni, ko ni salaini.
Nipa amọran awọn dokita kan pe ko yẹ ki wọn si pa konile-o-gbele ti, nitori bi wọn ṣe ni arun naa fojoojumọ gbilẹ si, Oba Akamọ sọ pe awọn dokita le sọ nitori iṣẹ ti wọn n ṣe, o ni ṣugbọn ibi ti gbogbo ẹ ti le ṣiṣẹ nibi ti wọn ba ṣagbekalẹ ẹ daadaa.
O ni pẹlu gbogbo ẹ naa, oun gba nnkan tawọn dokita sọ, nitori imọ ni koko, nigba ti wọn kọkọ sọ nipa korona, o lawọn eeyan sọ pe kin ni wọn tun sọ, laimọ pe o ti wa nilẹ tipẹ.
Kabiyesi ni Ọlọrun ko ni jẹ ka rogun korona fairọọs, ṣugbọn nnkan to ṣe pataki ni pe nnkan ti ijọba ba ni ka ṣe, ki a maa ṣe.,ẹni to ba ni ko fẹni ti ko ni ebi ki i wọnu kọrọ mi ko wọ ọ.
O ni  ni Itori yii awọn gbiyanju lori nnkan tawọn eeyan maa jẹ ati pe laarin ọjọ meji si mẹta awọn tun fẹẹ fawọn eeyan wọn lounjẹ lọfẹẹ.O wa dupẹ lọwọ Biṣọọbu Oyedepo, o ni wọn wa, wọn si fawọn ni irinwo apo irẹsi ati gaari naa.Ọmọọba Tunde Akamọ ati Akilẹ  Bayọ  fawọn to ku diẹ kaato ati opo ni ẹgbẹrun kọọkan, awọn bi ẹgbẹrun meji lo si jẹ anfaani ẹ.
O ni Ọmọọba Toyin Akọlade ati ọkọ ẹ ni wọn kọ fawọn eeyan bi ẹẹdgbẹta ni burẹdi ko to di pe oun naa ṣe eyi toun ṣe yii. Bakan naa lo ni eto tun lọ lọwọ lati fawọn eeyan bi ẹgbẹrun mẹta ni ibomu lọfẹẹ gẹgẹ bijọba ṣe pa laṣẹ pe ibomu ṣe pataki lakooko yii.
O wa rọ gbogbo ọmọ orileede yii lati pa ofin mọ, nitori oun mọ pe laipẹ yii ni arin naa yoo kuro lorileede yii.


No comments:

Post a Comment

Pages