Kayeefi nla niṣẹlẹ kan to waye ni
Owode- Ẹdẹ, nipinlẹ Ọṣun, si n jẹ fawọn ara agbegbe naa, nitori bi Ifẹoluwa
Fẹyintọla, ṣe gun iya ẹ lọbẹ pa, nitori o ka mọ ibi ti ọkọ ẹ ti n ba a sun.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ,
ẹni ọdun mejidinlọgbọn ni obinrin to gun iya ẹ pa ọhun, nigba ti iya ẹ, Ruth
Ṣodeya si jẹ mẹrinlelogoji., ohun ti wọn ni ọmọ yii sọ wọn lo ni o tipẹ tiya
oun ti n ṣe agbere.
Iwadii fi ye wa
pe ṣe ni Ruth iya Ifẹoluwa wa ki ọmọ ẹ ati ọkọẹ, to si sọ pe oun yoo lo ọsẹ
meji pẹlu wọn. Lọjọ tiṣẹlẹ yii waye, Ifẹoluwa lọ si ọja lati lọ ra nnkan ti wọn
fẹẹ se e.
Ṣugbọn jẹbẹtẹ
gbe ọmọ le e lọwọ nigba to wọle to si ka iya ẹ ati ọkọ ẹ mọ ori bẹẹdi ti wọn jọ
n sun,tawọn mejeeji si n kona fun ara wọn labẹ, bo ṣe ri wọn ni jinnijinni da
boo.
Yara idana wọn
lo gba a lọ to si mu ọbẹ, ko si besubẹgba, to fi gun iya ẹ lọbẹ ni aya,
tobinrin naa si ku loju ẹsẹ, koda, a gbọ pe o fẹẹ gun ọkọ ẹ yii amọ ti ori ko o
yọ.
Ninu ọrọ ti wọn ni Ifẹoluwa sọ ni teṣan
awọn ọlọpaa, wọn lo ni iwa agbere ti gbe iya oun wọ latigba tawọn ti wa ni
kekere, to jẹ pe ko si ọkunrin ti ko le ba a sun.
O ni bo ṣe maa
n yan baba oun jẹ nigba tiyẹn wa laye, o ni ẹdun ọkan lo jẹ foun bi iya oun ṣe
wọ ara ẹ nilẹ debi pe oun ka a mọ ibi ti ọkọ oun ti n ba a sun.
O ni boun ṣe kawọn mejeeji loun lọ
mu ọbẹ lati fi gun awọn mejeeji pa, ṣugbọn ti ori yọ ọkọ oun, o ni iwa itiju
nla lo jẹ foun. Ni bayii, Ifẹoluwa ti wa ni teṣan awọn ọlọpaa, tawọn yẹn si ti
bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ ọhun.
|
No comments:
Post a Comment