Iku alaboyun ti korona pa ti ko wahala ba awọn Dokita ati Nọọsi FMC Idi Aba - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday 3 May 2020

Iku alaboyun ti korona pa ti ko wahala ba awọn Dokita ati Nọọsi FMC Idi Aba


Inu ibẹru bojo lawọn dokita atawọn nọọsi  ile-Iwosan FMC, Idi Aba, niluu Abẹokuta wa bayii, ti wọn si n kun fun adura gididi nitori alaboyun kan  ti wọn fura si pe o ni arun korona to ku lojiji lakooko ti wọn reti abajade esi ayẹwo ti wọn ṣe fun un.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, Ọkunrin kan ni wọn sọ pe wọn gbe wa si ọsibitu naa lọjọ Aje, Monde, ọsẹ yii ti abajade esi ẹ si jade pe arun korona fairọs lo n ba finra, ti wọn si n gbe lati ibikan si ikeji latigba ti wọn ti daa duro.

Ẹnu ẹ ni wọn sọ pe wọn wa ti wọn tun fi gbe obinrin alaboyun wa sibẹ, ayẹwo ni wọn ṣe fun, ti wọn si n reti abajade ki o to di pe o gbẹmi mi, eyi lo si fa tawọn Dokita ati Nọọsi fi ko sinu wahala, nitori gbogbo awọn to tọju ẹ, ni wọn ti n tọpasẹ wọn bayii.

Gbogbo awọn eeyan wọnyii ni wọn si ti sọ fun un pe ki wọn lọ wa ninu yara ipamọ ti wọn ti n ṣayewo wọn, bi iroyin si ti jade ni awọn Dokita atawọn nọọsi yii ti n sa kijokijo, ti wọn si ni kawọn araalu fi adura ran awọn lọwọ, nitori wọn ko mọ iye awọn tawọn mejeeji ti fọwọ kan tabi tọju  nigba ti wọn gbe wọn de ọsibitu FMC,Idi Aba.

Dokita Ashimi ni wọn sọ pe o jẹ ọkan lara awọn dokita to tọju awọn ti wọn faragba arun korona ọhun.

No comments:

Post a Comment

Pages