Ọkan awọn
gbajumọ oṣere-binrin onitiata tirawọ ẹ n yọ, Oluwakẹmi Akinpẹlu ti sọ pe ọjọ
manigbagbe toun ko le gbagbe nidii iṣẹ tiata lọjọ ti ọga oun sọrọ soun nita
gbangba lori nnkan toun ko ṣe, ti omi si bẹrẹ si ni jade loju oun.
Obinrin yii
sọrọ naa lakooko to n ba oniroyin wa fọrọjomitoro ọrọ, o ni loootọ loun nifẹẹ
si ere tiata toun ṣe ati pe oun ko ro pe nnkan wa to le yọ ọ kuro lẹmi oun,
nitori lati ọdun 2013 toun ti wa lẹnu ẹ ko sigba kan
toun kabamọ ri.
Onitiata ọhun tun
sọ pe oun ko ṣadeede bẹrẹ iṣẹ yii ati pe oun ni ọga to kọ oun ni tifun-tẹdọ iṣẹ
naa. O fikun un pe ‘’ Ko si keeyan ma ni idojukọ lori iṣẹ
to n ba ṣe ṣugbọn eyi temi ba pad to jẹ akọkọ ni pe oju mi o tii di ilu mọn-ọn
ka, ti wọn ba pe mi si lokeṣan, wọn ko nii tọju wa daadaa bi awọn ti wọn ti ni
orukọ nidii ẹ, bẹẹ awa ṣiṣẹ daadaa ju wọn lọ’’
Oluwakẹmi tun
sọ pe oun yatọ sawọn ti obi wọn ki i gba fun wọn latilẹ lati ṣe tiata, nitori
pe latigba toun ti bẹrẹ ni wọn ti fi ifẹ wọn han si.Lara awọn to pe ni awokọṣe
nidii iṣẹ ni Bimbọ Ọshin, Bukky Wright, Ṣọla Ṣobọwale,
Ibrahim Chatta ati bẹẹbẹẹ
Nigba to n sọ
nipa awọn fiimu to ti kopa, obinrin yii ni o ti pọ ṣugbọn lara wọn ni Aṣiṣe nla, O ku diẹ, Ọrẹ mi, Kadara ni, ati bẹẹbẹẹ lọ. O ni
pẹlu iṣẹ tiata toun ṣe yii, ọrọ ọkunrin onitiata ko jẹ nnkankan loju oun,
nitori pe oun kọ loun ba lọ sibẹ.
Obinrin yii tun
fesi lori ibeere iha ti ọkọ ẹ kọ si nidii iṣẹ to n ṣe, o sọ pe ‘Alatilẹyin mi
lọkọ mi, nitori o fọwọ si iṣẹ ti mo n ṣe yii, nitori o mọ pe emi naa ki i
sọmọkọmọ’’.
O wa ni gbogbo
igba tinu oun maa n dun ju laye oun ni toun ba ti wa ni lokeṣan. Nitori oun mọ
pe ọjọ iwaju oun yoo dara nidii ẹ. O ni oun tun fi iṣẹ irun didi kun iṣẹ toun
ṣe, nitori lakooko yii iṣẹ tiata ko ṣe da nikan ṣe.
|
No comments:
Post a Comment