Fun itẹsiwaju
ipese ounjẹ fawọn to ku diẹ kaato nipinlẹ Ogun fun ti komile-o- gbele to n lọ
lọwọ fun arun ti korona fairọs to wa nita, wọn tun ti bẹrẹ igbesẹ keji nipa
iranlọwọ yii nipa fi fawọn akanda eeyan elere idaraya lẹbun lọfẹẹ.
Nibi eto naa to
waye nijọba ibilẹ Ijẹbu-Ode ni kọmisannsa feto isuna,to tun jẹ oludamọran
Gomina lori ọrọ aje, Ọgbẹni Dapo
Okubadejo, ti sakiyesi pẹlu bi gbogbo bi nnkan ṣe n lọ lagbaye paapaa julọ
lawọn orileede to ti ni idagbasoke jẹ ki
wọn mọ pe o yẹ ki igbesẹ tete waye lori arun korona to gbode yii.
Ninu atẹjade ti
Arabinrin Fọlake Ade-Adeniji ati Oluwaṣẹgun
Craig, ti wọn jẹ akọwe iroyin nileeṣẹ eto isuna nipinlẹ Ogun fi sita, ni
kọmiṣanna ọhun ti sọ pe nitori bi arun naa ṣe n gbilẹ si nijọba ṣe wa ọna lati
gbogun, nipa ipese ilera bẹẹ ni itaniji tun lọ ni ọkan-ọ-jọkan lati maa la awọn
eeyan lọyẹ lori bi wọn ṣe le dena arun yii. Eyi to sọ pe ko bọwọ fẹnikẹni lati
mu yala ẹsin, ọjọ-ori tabi ipo lawujọ.
Okubadejọ tun fi
kun ọrọ ẹ pe nipa ẹbun tijọba ipinlẹ naa fawọn eeyan, o ni ẹẹdẹgbẹta ile lo ti
janfaani ẹ ni abala akọkọ nigba pẹlu
iranlọwọ awọn ẹlẹyinju aanu lawujọ.
Kọmiṣanna ni
awọn to ku diẹ
kaato, awọn arugb atawọn mii in ni wọn ti jẹ anfaani naa, pẹlu ileri pe eto ti
n lọ lọwo lati ṣe iru eto bayii fawọn ọdọ to wa kaakiri ipinlẹ ọhun.
Okubadejo wa lo akoko naa lati dupẹ
lọwọ awọn ẹlẹyinju aanu fun iranlọwọ wọn wọ, ti nnkan le koko yii bẹẹ naa lo
tun ki awọn araalu naa fun bi wọn ṣe pa ofin mọ. O ni awọn ti ṣi ikanni kan
lori ẹrọ ayelujara fun ẹnikẹni to ba ni iranlọwọ lati ṣe bẹẹ ni akaunti ti wọn
le sanwo si tun wa, nitori ki i gbogbo nnkan nijọba le ṣe. O wa gbawọn eeyan
nimọran lati pa ofin jijina sira ẹni mọ.
Ko to akoko yii lawọn eeyan
Oke-Irojo nijọba ibilẹ Ijẹbu-Ode ti kọkọ jẹ anfaani ẹbun ounjẹ lọfẹẹ yii. Nigba
ti wọn n dupẹ lọwọ ijọba lorukọ awọn akanda elere idaraya ati eeyan agbegbe Oke-Irojo,
Arabinrin Ọladipupọ Oluwakẹmi and Alaaji Lasisi Ọrẹṣẹgun ni wọn ti ṣeleri pe
gbogbo awọn ibi to ba tọ lawọn yoo pin kinni naa de.
No comments:
Post a Comment