O ma ṣe o;Wọn lawọn kọsitọọmu yinbọn pa Biliwanu ni Owode- Idiroko - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday 1 May 2020

O ma ṣe o;Wọn lawọn kọsitọọmu yinbọn pa Biliwanu ni Owode- IdirokoBeeyan ba jẹ ori ahun ko si ki omi ma bọ loju ẹ to ba debi ti ibọn awọn asọbode, ti wọn pe ni kọsitọọmu ti pa Ọdọmọkunrin, ọmọ ọdun mẹẹẹdogun kan ti wọn pe orukọ ẹ ni Riliwan Bello.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, laaarọ ọjọ Ẹti, Furaidee, ana, ni wọn sọ pe iṣẹlc naa waye ni garaji Owode- Idiroko.Ọmọleewe girama Area community High school  to wa ni Owode bakan naa ni wọn pe ọmọ ọhun, ati pe yara ikawe girama giga akọkọ SS1 ni wọn sọ pe o wa.

Iwadii fi ye wa pe ṣe lawọn asọbode yawọ garaji Owode, ti wọn ni wọn bẹrẹ si ni fọ ṣọọbu, ti wọn si n ko apo ṣuga jade, bẹẹ ni wọn sọ pe wọn tun yinbọn soke lati fi le awọn eeyan sa.

Ara ọta ibọn ti wọn sọ pe wọn yin soke yii lo ba Riliwan lori, ti ori ẹ si fọn ka, to si ku loju ẹsẹ, gbogbo akitiyan awọn to wa nibi iṣẹle ọhun lati doola ẹmi ẹ lo ja si pabo.

Oniroyin wa gbọ pe bawọn aṣọbode ọhun ṣe ri nnkan to ṣẹle ni wọn ti sa lọ, eyi lo si mu kawọn ara gareeji yii tu jade lati fi ehonu wọn han. A gbọ pe ọja ni Riliwan kiri tawọn eeyan ọhun ṣe dẹmiu ẹ legbodo.

Gbogbo akitiyan wa lati gbọ tẹnu awọn aṣọbode lori iṣẹlẹ yii lo ja si pabo nitori bi agbẹnusọ wọn, Malwaida ṣe sọ pe oun yoo pe wa ṣugbọn ti ko pe pada titi taa fi n kọ iroyin yii.

No comments:

Post a Comment

Pages