Konile-o- gbele tẹsiwaju nipinlẹ Ogun dọjọ kẹsan-an oṣu yii. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday 1 May 2020

Konile-o- gbele tẹsiwaju nipinlẹ Ogun dọjọ kẹsan-an oṣu yii.



Gomina Dapọ Abiọdun ti sọ di mi mọ pe ofin konile-o-gbele nipinlẹ naa si n tẹsiwaju dọjọ kẹsan-an, oṣu yii lati fi le ba ọsẹ marun-un tijọba apapọ la silẹ fun ti arun korona to n tan kaakiri orileeede yii.

O sọrọ yii lakooko to n ba awọn oniroyin sọrọ lori ibi ti nnkan de lati ọsẹ mẹrin tawọn araalu ti wa ninu ofin konile-o-gbele ọhun. O sọ pe bo tilẹ jẹ pe laaarin ọsẹ kan to ku yii, lo ti faye isinmi silẹ fawọn araalu lọjọ Aje, Monde,Ọjọruu, Wẹsidee ati ọjọ Ẹti Furaidee ọsẹ to n bọ laaarin aago meje aarọ si marun-un irọlẹ.

O sọ pe pẹlu awọn iwadii tawọn ti ṣe ọpọ awọn to lugbadi arun naa lo jẹ pe lati ẹnu ibode, ti wọn wa lati orileede mii in ni wọn  kasa ẹ wa si ipinlẹ Ogun, o ni akọsilẹ tawọn ṣe lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu yii fi han pe awọn mẹrinlelogun lo de si Iluṣin ni Ogun Waterside laaarin wakati mẹrinlelogun, nigba ti wọn si mu mejila ninu wọn ni ijọba ibilẹ Odogbolu.

Gomina tun ṣalaye pe pẹlu erongba awọn lati ma jẹ ki ebi pa ara ilu, o ni ijọba oun tun fawọn ẹgbẹrun lọna ogun awọn ọdọ ni ounjẹ ọfẹ lawọn ijọba ibilẹ gbogbo to wa nipinlẹ naa.

O ni pẹlu bi konile-o- gbele naa yoo ṣe tẹsiwaju bẹẹ naa ni ofin iṣede to Aarẹ orileede yii kede ẹ pe yoo bẹrẹ laaarin aago mẹjọ alẹ si mẹfa owurọ yoo bẹrẹ lọjọ Ajẹ, Monde, to n bọ yii.

Abiọdun wa lo akoko ọhun lati ran awọn araalu leti pe lilo awọn ibomu nigboro ti ṣe pataki bayii ati pe ẹnikẹni ti wọn ba mu lailo yoo foju winna ofin ijọba.

O ni kawọn araalu ri pe wọn lo ibomu wọn nibikibi ti wọn ba n lọ.O ni ijọba oun ti pese miliọnu kan ibomu ti wọn si ti pin kaakiri ipinlẹ Ogun fawọn araalu paapaab awọn ara ọja, onimọto, oniṣẹ-ọwọ atawọn mii in gbogbo.

Abiọdun wa sọ pe o ti wa di dandan fawọn ero bọọsi lati ma ko ida meji ero ti wọn n ko tẹlẹ, kawọn ọlọkada NAPEP ma ko ju ero kan, bẹẹ lo ni awọn ọlọkada gan-an ko gbọdọ maa gbe ju ero kan lọ.

Bẹẹ lo ni awọn bi ileewe, ile ijọsin, ile igbafẹ, ṣi wa ni titi pa di akoko yii.O wa dupẹ lọwọ gbogbo ọmọ ipinlẹ Ogun fun atilẹyin wọn latigba ti konile-o- gbele ti bẹrẹ pẹlu adura pe wọn yoo bori ẹ laipẹ yii.

   

No comments:

Post a Comment

Pages