Fun igba keji laarin osẹ meji, ijo Kerubu ati Serafu, Ebenezer Communion, to wa ni Oke-ibukun, niluu Abẹokuta fawọn ọmọ ijọ lẹbun ounjẹ fun ti konole-o-gbele to n lọ lọwọ nitori arun korona to gbode kaakiri.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ọjọ Ẹti, Furaidee, onii yii ni wọn tun
fawọn ọmọ ijọ naa lẹbun ounjẹ, eyi ti wọn bẹrẹ si nii pin lati nnkan bi aago mẹsan-an
aarọ. Awọn nnkan ti wọn fawọn ọmọ ijọ naa ni ẹwa, gaari ati alubọsa.
Ni nnkan bi osẹ meji sẹyin ni wọn fun wọn ni Irẹsi, ẹwa
ati gaari. Ṣe ni inu awọn ọmọ ijọ naa dun fawọn ohun ijọju ti wọn ṣe fawọn yii,
ti wọn si n sadura fawọn ti wọn ṣagbekalẹ ounjẹ naa fun wọn.
Idi ti wọn fi ṣagbekalẹ ounjẹ ọfẹ naa fawọn ọmọ ijọ wọn ni
lati ran wọn lọwọ lori konile-o-gbele, ki wọn le maa ri nnkan jẹ. Nitori bi
ounjẹ wa ti wọnu, nnkan yooku kere.
No comments:
Post a Comment