Olu tilu Itori,
Ọba Fatai Akorede Akamọ, ti ranṣẹ ayọ fun ti ọjọọbi aadọta ọdun, Aarẹ ọna
Kankafo tilẹ Yoruba, Iba Gani Adams. Ninu atẹjade kan ti Ọba alaye naa fi ranṣẹ
si wa lo ti ẹni to jẹ adari ẹgbẹ OPC naa ku ayẹyẹ naa.
O sọ pe pẹlu
idunnu loun fi ba a yọ ati pẹlu awọn aṣeyọri ẹ to fi di igba ati akoko yii, o
ni aṣaaju rere ti ko ṣe fọwọ rọ sẹyin, to ṣi ṣe mu yangan lawujọ ni Aarẹ ọna
kankafo kẹẹdogun ọhun.
Olu- Itori sọ
pe ko si awitunwi asan kan rara, pẹlu ọjọ ori Iba Gani Adams, nitori o ti ko
awọn ipa to jọju manigbagbe fun iran Yoruba, eyi ti ko ṣe lafiiwe. O wa gbadura
pe awọn alaalẹ yoo tubọ mu gbooro lati maa dagba si ninu ọgbọn ati oye, ko si
ni ku iku aitọjọ.
Bẹẹ lo tun ni
latigba ti Aarẹ Ọna kankafo ti depo to wa yii,
lo ti sa ipa ati gbogbo agbara pẹlu ọgbọn ati igboya ṣe awọn nnkan to ba jẹ ti
iran ọmọ Yoruba lọna tootọ. Ọpọ igba lo ni o ti duro fun ipenija awọn Yoruba
lati ma jẹ kawọn kan maa halẹ mọ wọn.
O wa ni bi Iba ṣe n darapọ mọ ọjọ
ori awọn agba, ki Ọlọrun tubọ jẹ ko dagba si ninu ẹmi, pẹlu aṣeyori lori awọn
gbogbo nnkan to ba ti dawọle lọjọ iwaju. Bẹẹ lo tun ba gbogbo ọmọ ilẹ Yoruba yọ
ayọ nla ọjọọbi aṣaaju nla naa.
No comments:
Post a Comment