Pẹlu bi Aarẹ ọna Kankafo gbogbo ilẹ Yoruba, Iba Gani Adams ṣe pe aadọta ọdun to de ilẹ alaaye, Kọmureedi Samson Oyerinde Ọtẹpọla tọpọ awọn eeyan mọ si Idi Amin, to jẹ alakoso fẹgbẹ OPC ni ijọba ibilẹ idagbasoke Igbogbo Bayeku, to si tun jẹ oluranlọwọ Pataki fin akanṣe iṣẹ fun Aarẹ ỌnaKakanfo, ti ki Iba Abiodun Ige Gani Adams ku oriire fun ayẹyẹ ọjọọbi aadọta ọdun.
Gẹgẹ bi atẹjade ti wọn fi sita, ni
Idi Amin atawọn eeyan ẹ ti rọjọ adura le ẹni to jẹ Aarẹ ọna KAnkafo kẹẹdogun pe
ki Ọlọrun lọra ẹmi ẹ fawọn, ko si dagba ninu agbara ati ẹmi.
Nibẹ tun lawọn ti wọn jẹ alakoso
fẹgbẹ OPC kaakiri naa ti gbadura ọlọkan-ọ-jọkan fun aṣaaju ilẹ Yoruba fawọn ipa
to ti ko fun ilọsiwaju ilẹ Yoruba.
Lorukọ OPC Igbogbo Bayeku ni Idi Amin ti gbadura pe ki
Ọlọrun ma jẹ ki baba wọn, Iba Gani Adams lo iyooku aye ẹ ninu ipọju ati wahala.
Ati pe bo ṣe jẹ mu idunnu ba ọpọ mọlẹbi bẹẹ naa ni ki ayọ ma ṣe foun naa silẹ.
Igbakeji alaga ẹgbẹ naa, Sọla
Ogunfuyi ninu adura ẹ lo ti ni sọ pe ki
Ọlọrun jẹ ki Iba Gani Adams lo ọpọ ọdun laye ninu alaafia.
Lawal, toun jẹ
akọwe toun jẹ ojulowo ọmọ Aarẹ dupẹ lọwọ Ọlọrun fun pe o jẹ ki baba oun ri ọjọọbi
naa layọ ati alaafia.Lekan Durojaye, olupolongo ẹgbẹ ṣapejuwe Ọlọjọọbi naa gẹgẹ
ẹni to dara ju lagbaye, o wa gbadura pe ki Ọlọrun jẹ ko ṣe ọpọ ọdun laye
Awọn yooku ti wọn tun ṣadura lọjọ
naa ni Iya Oodua jẹnẹra, Kofoworola Ajetunmobi, Toyin Awi, Adedayo Afolabi, Olayinka
Kazeem (Eba), Aliu Pebora.
Awọn alakoso ti wọn tun ranṣẹ ikini
ni ku oriire ni
Arabinrin Modupe Ayeni, Wahab Sodiq, Arabinrin
Aina Quadri,
Adeniyi Adeleke –Alowonle, Idowu
Quadri,atawọn yooku.
|
No comments:
Post a Comment