Ọba Eselu tilu Iselu, Ọba Akintnde Akinyẹmi ti sọ pe awọn fun ileeṣẹ asọbode iyẹn kọsitọọmu lọjọ mẹrinla lati tọrọ aforiji nita gbangba lori ẹni ti wọn pa, ti wọn sọ pe fayawọ ni, o ni bi bẹẹkọ awọn yoo pade nile-ẹjọ.
Ọba alaye naa sọ pe ko si fayawọ kankan ti wọn pa ninu
igbo naa bi ko ṣe ẹni ẹlẹni kan, to jẹ agbẹ, torukọ ẹ n jẹ Kehinde Ogunji, to jẹ
ẹni ọdun mẹẹdọgbọn, oun lo ni awọn kọsitọọmu pa nigba to n ti oko bọ pẹlu ekeji ẹ.
Ọba Iselu sọrọ yii lati fi tako atejade tileesẹ kọsitọọmu
gbe jade pe fayawọ lẹni ti wọn pa naa, idi niyii ti Oba fi sọ pe awọn fun wọn
lọjọ mẹrinla lati fi tọrọ aforiji fun irọ ti wọn pa ọhun bi bẹẹ kọ awọn ti ṣetan
lati gbe wọn lọ sile-ẹjọ.
Agbẹnusọ awọn kọsitọọmu, Abdullai Maiwada, lo sọ lọjọ
Aiku, Sannde, to kọja pe awọn afurasi fayawọ kan lo doju ija kọ awọn oṣiṣẹ wọn
lọna Eselu ni Igua nijọba ibilẹ Yewa North.
O fikun ọrọ ẹ pe nibi tawọn ti jọ doju ija kọ ara wọn ni
awọn ti pa ọkan ninu wọn, Ṣugbọn ọba alaye naa sọ pe irọ patapata ni Agbẹnusọ
awọn kọsitọọmu naa pa, o si fi tabuku ara ẹ.
Ọba Akinyẹmi fidi ẹ mulẹ pe ọta ibọn tawọn asọbode naa
yin lati fi le awọn ti wọn le lo ba Kẹhinde ki i ṣe pe o wa lara awọn ti wọn n
le. O fi kun ọrọ ẹ pe iyawo meji, ọmọ marun un atawọn ẹbi ni ọkunrin tawọn
asọbode naa dẹmi ẹ legbodo fi silẹ saye lọ.
Ọba
ṣalaye siwaju pe bi wọn ṣe pa Kẹhinde ni wọn gboku sori ọkada pẹlu ikeji ẹ ti
wọn pada sile lati sọ fun baba ẹ pe awọn asọbode ti pa ikeji oun, O ni fayawọ
to gbe irẹsi ti wọn n le Sunday Alabo lorukọ ẹ, Igua lo ti wa, Bennin lo sọ pe
o ti n bọ.
O wa rọ awọn ọlọpaa lati lọ mi Sunday, ki wọn si beeere
lọwọ ẹ pe ṣe ẹni ti wọn pa wa lara awọn ọmọọṣẹ ẹ, lati fi le ri okodoro.
O ni bi oun ṣe n sọrọ yii awọn ẹbi Oloogbe naa ti lọ sọ
bọrọ ṣe jẹ ni teṣan ọlọpaa to wa ni Ọja-Ọdan, o ni awọn ọlọpaa n duro de awọn
asọbode ti wọn pa Kẹhinde lati wa si Eleweran, ki wọn wa sọ bo ṣe jẹ, ṣugbọn to
ni wọn ko tii yọju.
Ileeṣẹ
awọn ọlọpaa nipinlẹ Ogun naa si ti sọ pe awọn ti gbọ nipa iṣẹlẹ naa tawọn si ti
bẹrẹ iwadii lee lori.
No comments:
Post a Comment