Olu- Itori fẹgbẹrun eeyan lounjẹ lọfẹẹ - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Monday 27 April 2020

Olu- Itori fẹgbẹrun eeyan lounjẹ lọfẹẹ


Ṣe ni inu awọn eeyan ilu Itori dun ṣẹkẹ nigba ti ọba ilu naa, Ọba Fatai Akorede Akamọ, fẹgbẹrun kan, awọn eeyan lounjẹ ọfẹ. Fun ti iranwọ to ṣe fun wọn lori konile-o- gbele to n lọ lọwọ nipinlẹ Ogun, nitori arun korona.

Ninu ipolongo kan to pe akori ẹ ni ẹ jẹ ka bọ ẹgbẹrun eeyan ni Ọba ọhun ti bẹrẹ lati fi gbogun ti ebi laaarin awọn eeyan tiẹ. Ohun ta gbọ ni pe gbogbo awọn eeyan to wa lagbegbe ati igberiko ilu naa ni lo fun lanfaani ounjẹ ọfẹ to fun wọn.

Iwadii fi ye wa pe Ọba to wa nipo kin-in-ni gbe igbesẹ lati fawọn eeyan lounjẹ nibi tawọn eeyan ti wa si aafin ẹ lati gbaa.  Gbogbo awọn to si wa nibẹ naa ni wọn ṣadura fun Ori ade nipa bi ko ṣe jẹ ki ebi pawọn sile lakooko konile-o- gbele to n lọ lọwọ yii,
.
Ninu ọrọ Kabiyesi, Ọba Fatai Akorede Akamọ, lo ti sọ pe latigba ti wahala ọrọ konile-o gbele ti bẹrẹ loun ko ti sun toun wo ọna toun le gba lati ran awọn eeyan ẹ lọwọ lakooko korona yii, idi niyii toun fi ranṣẹ pe Ọgbẹni .Nathaniel Ṣodipo, tawọn kan pe ni Uncle Nath.

O lawọn jọ sọrọ nibẹ lawọn ti fẹnu ko lati wa ọna ounjẹ pajawiri fawọn eeyan, o ni boun ṣe kan ṣawọn eeyan Pataki lawujọ lati dide iranlọwọ ki wọn le gbogun ti ebi lakooko konile- o- gbele naa.

NIbi eto ẹ jẹ ka bọ ẹgbẹrun eeyan  ti Kabiyesi rawọ le, la gbọ pe awọn eeyan bii  Babalaje tiluu Itori Egba , Oloye Kazeem Odeyeyiwa,  Oloye Amuludun Itori Egba, Nathaniel Ṣodipọ ati awọn mii in ti dide iranlọwọ. Bẹẹ ni wọn tun dupẹ lọwọ Ọmọọba Kayọde Kọlade ati iyawo ẹ fun ipa tawọn naa ko lori ipese ounjẹ yii.











No comments:

Post a Comment

Pages