Ijiya ẹṣẹ wa fẹni ti ko ba bo imu ẹ nipinlẹ Ogun latọjọ kin in-ni oṣu to n bọ- Dapọ Abiọdun - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday 24 April 2020

Ijiya ẹṣẹ wa fẹni ti ko ba bo imu ẹ nipinlẹ Ogun latọjọ kin in-ni oṣu to n bọ- Dapọ AbiọdunGomina ipinlẹ Ogun, Dapọ Abiọdun, ti sọ pe ẹnikẹni ti ko ba faṣọ bomu tọwọ ba tẹ yoo foju winna ofin ijọba bẹrẹ lati ọjọ kin-in-ni, oṣu karun-un ọdun yii.
Ọkunrin naa sọrọ yii nirọlẹ yii lakooko to n ṣe ipade pọ pẹlu awọn oniroyinn ni Ipẹru, lori ibi ti nnkan de lori wahala ti arun korona da silẹ, eyi to mu kawọn eeyan wa ni konile-o-gbele lati nnkan bi ọsẹ mẹta sẹyin.
Gomina sọ pe ẹnikẹni tọwọ ba tẹ ni yoo wa ni yara ifipamọ ti wọn ti n fawọn to ba ki arun naa si fọjọ mẹrinla, lẹyin naa ni yoo tun jiya lati sin ilu pẹlu.
O fikun ọrọ ẹ pe idi pataki tawọn fi gbe igbesẹ naa ni lati dena arun korona to n tan kaakiri ipinlẹ yii. O ni o ti di dandan fawọn araalu bayii lati maa fi aṣọ bomu wọn.
Dapọ Abiọdun tun ṣalaye pe’’ Lori ofin lilo aṣọ ibomu ti mo mẹnuba yii, a ti n gbero lati ṣagbekalẹ ofin lilo aṣọ ibomu, to ba ya a maa bẹrẹ lati wo iru ijiya fẹni to ba tapa si ofin yii.
Ṣugbọn mo fẹ mu dayin loju pe ẹnikẹni tọwọ ba tẹ to tapa si ofin aibomu yii, a o fi pamọ sibi ti wọn fawọn ti wọn fara pamọ lori arun yii si, nitori ko ma ba fi tiẹ ko ba ẹlomii in’’
Ọjọ mẹrinla lẹni tọwọ ba tẹ naa yoo fi wa nibẹ, bakan naa ni yoo tun sin ilu lati fi kọgbọn, nitori idi eyi ati fun anfaani yin, ibikibi ti ẹ ba ti n lọ, ki ẹ maa bo imu yin.’’
O tun sọ pe lati ọjọ Ẹti, Furaidee, to n bọ yii, o ti di dandan fawọn eeyan ipinlẹ Ogun. A si ti ṣetan lati bẹrẹ si nii pin  awọn nnkan fawọn araalu.
O ni awọn si ti mura lati bẹrẹ igbesẹ fun awọn aṣọ iboju ko to di ọjọ kin-in-ni oṣu karun-un tofin ẹ yoo fi di mimulo.
Gomina ni Awa gẹgẹ bijọba a yoo pese milọnu meji aṣọ ibomu fawọn taa lero pe wọn ko lagbara lati le ra. ṣugbọn ẹnikẹni to ba fẹ lọ sidi ọja tabi okoowo ẹ gbọdọ maa fi nnkan bomu’’

Ṣugbọn sa o, o ni konile-o-gbele yoo tun bẹrẹ lati ọla lọ, nigba ti isinmi ranpẹ yoo waye lọjọ Aje, Monde, lati aago meje aarọ si meji ọsan.
Bẹẹ lo ni iru isinmi yii yoo tun waye lọjọruu, Wẹsidee ati Furaidee. l

No comments:

Post a Comment

Pages