Ọkan lara ilu to gbooro nilẹ Ẹgba ni Igbehin jẹ, nibẹ si ni Liṣabi ti wa. Ilu naa tan-an ka debi pe ilu ati abule to wa labẹ to ọọdunrun le ni aadọrin, ẹ. Laipẹ yii ni Ọba Festus Oluwọle Makinde,Ojoru jọba, Onigbehin tiluu igbeyin,nilẹ Ẹgba gba oniroyin wa lalejo ni afin ẹ to wa ni Mowe, nibi to ti ba wa sọrọ nipa ilu naa. Ohun to ba wa sọ ree.
Kin ni a n pe ni Ojoru-jọba?
Ọmọ Ojoru, oun ni mi. Oun lo kọ jọba nigbẹhin,awọn
babanla wa ni, nigba ti a kọ maa jọba, ẹni to kọ jọba ni ọmọ Ojoru, nitori ẹ la
ṣe n pe ni Igbẹhin.
Bawo ni Igbẹhin ṣe tẹdo?
Igbẹhin, gẹgẹ bi awọn yooku ni Ẹgba, a jọ wa tẹdo si Ẹgba
ni.Lati Ifẹ ondaye lati wa, a kọkọ gba Ọyọ lọ, nigba ta a n bọ, a tun pada si
Ibadan.latibẹ lati wa si Abẹokuta.
Ta ni a le sọ pe o tẹ igbẹhin do?
Awọn ẹni akọkọ ti wọn ko ogun de ibi yii, ni wọn tẹ Igbẹhin
do. Bi ẹ ba n gbọ Liṣabi, ọmọ Igbẹhin ni.Ninu awọn jagunjagun wa ni, nigba taa
de ibi, a kọkọ tẹdo sibi ti wọn n pe ni Odo-Igbẹhin.
Ibẹ ni Orile- Igbẹhin akọkọ, nigba taa kuro nibẹ, la tun
lọ si Orile-Igbẹhin keji oun lo wa lẹgbẹ Owode-Ẹgba,ibi ti a kọkọ de ni a ti bẹrẹ
si nii fọba jẹ.
Ọba ti akọkọ jẹ la n pe ni Lagunna.Nigba to waja ni
Okuribido naa jọba, nigba toun naa waja ni Ogunmọla tun jẹ. Nigba toun naa tun
lọ ni Ọṣọolu naa tun jọba.Oun lo waja ni 1904, nitori pe ọdun yii lo jẹ, o si
wa ni Ipebi, ibẹ lo si wa to fi waja.
Gẹgẹ bi itan ṣe sọ fun wa, nnkan bi oṣu kejila, ọdun 1904
lo jẹ, ko lo ọgbọn ọjọ tabi ko le diẹ to fi waja.Latigba naa la o ti jọba titi
to fi di 2004, la o ti jọba.
Iyẹn bi ọgọrun-un ọdun sẹyin lẹ o fi lọba niluu?
Bẹẹ ni, a dara fun ẹ
Kin ni o faa?
Nigba ti Ọṣọolu waja, itan nla ni, wọn gba ade ẹ, wọn fi
pamọ si Ake, nigba aye awọn oyinbo ni, ọba pọ nigba naa nilẹ Ẹgba, wọn wa n wọna
bi Ọba Ake yoo ṣe rọwọ mu lori awọn ọba yooku,
nitori ẹ ni wọn se gba ade ori ọba igbẹhin atawọn ọba yooku nigba naa.Iwọnba
ti mo le sọ lori ẹ niyẹn, abọ ọrọ la n sọ fọmọluabi.
Nigba to di ọdun 2004, ni Oloogbe Oloye Toye Coker, agbẹjọro
ni, oun lo sọ pe ka gbe igbesẹ ni Igbẹhin, bi a ṣe maa jọba ni igbehin, ko tiẹ
pe fun wa ni pada, nitori ọpọ ni ko mọ pe a ti jọba ri.
O ni ka wa ọna bi a ṣe maa sewe ẹ lọdọ Alake ana,Ọba
Oyebade Lipẹde, bi ẹ ba wo afin wa, aa ni gbọngan nibi taa fi sọri Oyebade Lipẹde,
a fi ṣeranti wọn ni, bẹẹ la ṣe ọkan naa taa pe ni gbọngan Oloye Toye Coker,
nitori a o le gbagbe iṣẹ ti wọn ṣe.
Ṣe ọmọ Igbehin lawọn naa?
Iya wọn lọmọ Igbehin,wọn kan jẹ ọkan lara oloye Ẹgba, gẹgẹ
bimo ṣe sọ, a gbọdọ maa ranti awọn ẹni rere, a jọ n ṣeto naa wẹrẹ, mo si ti di
Baalẹ nigba naa lọhun,Baalẹ tile-toko gbogbo igbẹhin ni 1997,ko to di ọdun
2000, ti wọn ni ka wa gbe igbesẹ.
A ṣe ṣe ṣe ko to di pe Coker jade laye,lẹyin to ku la tun
tẹsiwaju ko to di pe Ọba Lipẹde sọ pe ka wa jẹ ọba. O loun fẹ fun wa ni ọba
nitori pe awọn Awori fẹ gba ilẹ mọ wa lọwọ, o ni ka lọ wa ibikan ta o fi ijokoo
ọba yẹn si, awa Igbehin, a ronu sọtun, a ronu sosi, a wo gbogbo oko wa, eyi to
maa tobi daadaa, to jẹ pe bi a ba n bọ, a maa tete debẹ,emi gẹgẹ bi baalẹ
tile-toko, wọn ni ki n lọ ronu nipa ẹ.
Nigba to si jẹ pe emi naa ti n pe ipade awọn baalẹ nigba
naa, mo wa roo pe Mowe ni ka fi ibujokoo ọba yii si, nitori o wa ni oju titi.
Ibikibi ti wọn ba n wa ọba bọ, wọn yoo tete ri.
Ọba Lipẹde ni Olu-Mowe ni a maa pe ọba yẹn niyẹn o, awa
naa gba pe ka pe bẹẹ, emi gẹgẹ bi ẹnikan ti ko tiẹ mọ nipa ọrọ oye jijẹ nigba
naa, mo gba.
Ṣugbọn bi a ṣe n mura silẹ lati jọba lawọn ara Mowe sọ pe
awọn o gba, ki emi ti mo jẹ baalẹ tile-toko, ki wọn wa fi mi jẹ ọba Mowe,
nitori awọn lọmọ to le jẹ.
A si ti joye, nigba ti wọn sakitiyan kaakiri, ti wọn lọ
sile ijọba, ti wọn lọ sile Alake, nijọba wa kọ lẹta si igbimọ lọbalọba tilẹ Ẹgba
lọjọ kejila, oṣu kẹwaa, ọdun 2004.
Emi si ti jẹ Ọba Mowee lọjọ kin-in-ni, oṣu kẹsan-an,
2004.Nibẹ lawọn naa ti sọ pe loootọ Mowe ni awọn fi ijọba mi si, amọ ko yẹ kawọn
sọ ni Olu-Mowe, nitori ẹni to jẹ ọba yii baalẹ tile-toko lawọn pe tawọn ba waa
pẹ ni Olu-Mowee, bi abule kan ni yoo maa sejọba ẹ ninu gbogbo abule ọọdunrun le
aadọrin to n ṣakoṣo ẹ.
Igba naa niye wa sọ daadaa pe ki Ọlọrun ma jẹ ki wọn ṣe aṣiṣe,
ki wọn ku sọ di Olu- Igbehin, bo ṣe di Olu-Igbehin, ti wọn si kọ lẹta si ọba lọjọ
kejidinlogun, oṣu kẹwaa, 2004, lati yii pada lati Olu-Mowe si Olu Igbehin.
Ṣugbọn lọdun 2006, wọn fi igbimọ kan le lẹ nipinlẹ Ogun,
wọn pe ni awọn to n ṣatinṣe lori ọrọ ọlabade, nigba naa lawa ilu kọ lẹta si
igbimọ naa nigba ti oju wa la pe a ti jẹ ọba ri, Oni-Igbehin ni wọn n pe wọn.
Ko wa yẹ ko jẹ pe Olu-Igbehin ni wọn yoo pe wa,
nigba naa a lọ sibẹ, ni 2018, a tun kọ lẹta
sijọba lati ran wọn leti, wọn si fun wa
lesi pe awọn ti gbaa, bi mo ṣe jokoo yii, mi o ki i ṣe Olu-Igbehin mọ,
Oni-Igbehin ni mi.
Njẹ ijọba ti mu lẹta wa fun akọsilẹ pe ẹ ti di
Oni-Igbehin?
Wọn ko ti mu lẹta wa ṣugbọn nnkan tawọn oloyinbo n pe ni ‘Silent
is the Conception’ latigba taa ti mu lẹta
lọ, awa gba pe wọn ti n ṣe, bi wọn ko ba si ṣe, mo tun fi akoko yii ran wọn
leti lati ṣe.
Kin ni a le pe ni ọdun ooṣa to pa gbogbo yin pọ niluu
yii?
Ọdun Ogun lo pa wa pọ ti gbogbo wa jọ n ṣee ati ile ati
oko, nitori ẹ ni wọn ṣe maa n pe wa ni ọmọ Ogun, ọjọ mẹsan-an la maa fi n ṣe e
ninu oṣu kẹwaa.
O ni awọn nnkan ti a maa n ka, bi a ba fẹẹ ṣee, amọ laaarin oṣu
kẹsan-an si kẹwaa ni. A ni Ogun ile, to wa ni agboole wa ni Igbehin,nigba ti Ogun
Ita iyẹn wa ni isọ-igba ni Itoku.
Ipo wo lẹ wa ninu igbimọ lọbalọba nilẹ Ẹgba?
Mo jẹ ọkan lara wọn, gbogbo wa si jọ wa papọ
Wọn tiẹ ni ẹyin ọba alaye lẹgbẹ kan ti wọn pe ni
Heritage, ki lo wa fun?
Awa lọbalọba nilẹ Yoruba la wa ninu Heritage yii loootọ,nipa
iranlọwọ Ọlọrun, emi ni Baba Isalẹ wọn, ẹgbẹ yii jẹ ki a maa mọ bi nnkan ṣe n lọ
laaarin ara wa, o si tun wa fun awọn nnkan isẹmbaye laaarin wa.
Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun pe lẹyin igba ti mo jọba, ni wọn fi
mi ṣe agbatẹru, a ti ko ara wa jọ laipẹ yii ni Ile Ifẹ lọdọ Baba wa Ọọni. A si
ti fẹnuko pe lọdọọdun la o maa ṣe ni Ifẹ.
Kin ni a le pe ni eewọ niluu yii?
Igbehin lo tobi ju ni gbogbo ilẹ Ẹgba,mo sọ pe ọọdunrun
le ni aadọrin labule wa, ko si siluu kan ni Ẹgba to ni ọgọrun-un, nitori a pọ
onikaluku wa lo ni eewọ tiẹ.
Kin ni awọn aṣeyọri yin niluu yii?
Aṣeyọri pọ, nigba ti mo jẹ baalẹ tile-toko, afin taa wa
ninu ẹ yii, ko si titi, nibi, ọna oko
ni, nigba ti mo jẹ ọba, ko si afin ti mo maa de si, Abẹokuta lawọn eeyan ti maa
n wa ba mi.Gbogbo ọba to ba ti jẹ tẹlẹ ile wọn ni wọn maa n jokoo si, ti wọn ba
si ti gbesẹ, ẹni to ba tun jẹ, ile ẹ naa ni yoo jokoo si.
Inu mi dun pe Ọlọrun lo mi lati kọ afin nla,awọn eeyan
maa n sọ pe afin yii lo tobi ju nipinlẹ Ogun. A ni kootu majisireeti laafin
yin, bẹẹ lawọn gbọngan loriṣiriṣi. A ni gbọngan ta a fi sọri Liṣabi, nitori ọmọ
ni.
Ipa wo ni Igbehin ko lakooko ọdun Liṣabi?
Igbehin lo yẹ ki wọn ti maa ṣọdun Liṣabi, ṣe lo dabi pe wọn
kan fọwọ ọla gba wa loju ni, nigba temi
si je Baalẹ, gbogbo nnkan ti wọn ba fẹẹ fi ṣerubọ nigbo Liṣabi, igbehin lo n fa
silẹ.
Boya iranlọwọ kan wa sọwọ Ẹgba tawa ko mọ, ni wọn ko ṣe jẹ
ka mọ bi wọn ṣe n ṣe, wọn ko fẹẹ ki owo ti wọn n gba han si igbẹyin.
No comments:
Post a Comment