Oloye Bayọ Dayọ, alaga fẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ogun, ti sọ pe ko sigba kan toun gbowo tabi abẹtẹlẹ lọwọ Ọnarebu Ladi Adebutu. Ati pe bi atunto yoo ṣe ba ẹgbẹ naa loun ba kaakiri.
Ọkunrin naa sọrọ yii lakooko to n ba oniroyin wa sọrọ
lori foonu lori ẹsun ti Sẹnetọ Buruji Kashamu, oludije fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ
oṣelu PDP nipinlẹ Ogun fi kan alaga naa gbe o gba ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un naira
lọwọ Adebutu lati fi ta ẹgbẹ naa.
Ọkunrin naa sọ pe to ba di inu oṣu karun-un ọdun yii loun
yoo gbe ipo toun wa ninu ẹgbẹ naa silẹ, ati pe ni gbogbo igba toun fi wa nibẹ
awọn ko mọ ju kawọn gbe ara wọn lọ sile- ẹjọ lọ, tiyẹn si mu ifasẹyin ba ẹgbẹ
naa.
Ati pe ọpọ awọn to jẹ oloye ẹgbẹ naa ni wọn ti fipo silẹ
tawọn fẹlomii-in dipo wọn, Idi niyii toun ṣe pinnu pe kawọn ṣe atunto, ki wọn
ye fojoojumọ lọ sile-ẹjọ, iyẹn lo sọ pe ko tẹ Buruji lọrun.
O ni oun kọ lẹta si agbẹjọro awọn pe ki wọn sinmi lati
maa pẹjọ, isọkan lawọn fẹ lakooko yii. O ni awọn si ti bẹrẹ igbesẹ, koda ipade
gbogbogboo ẹgbẹ ti wọn yoo ṣe lawọn ti fẹnuko ki igun mejeeji ni aṣoju nibẹ.
Gbogbo awọn igbesẹ yii lo ni ko tẹ Kashamu lọrun, to ni oun
gbowo nla yẹn, o ni ṣe eeyan le gbe miliọnu lọna ọgọrun-un naira silẹ fun eeyan,
irọ nla lo sọ pe o pa mọ oun.
Bẹẹ lọkunrin naa tun sọ pe lootọ ipo agba ẹgbẹ lawọn fi Kashamu si ati pe oun
lo n gbọ bukata ẹgbẹ naa ṣugbọn iyẹn ko sọ pe ko maa wa ilọsiwaju ẹgbẹ.
O wa pari ọrọ ẹ pe pẹlu gbogbo atunto tawọn igun mejeeji
n ṣe lọwọ, o daju pe ẹgbẹ naa yoo di ọkan pada.
No comments:
Post a Comment