Alaga fẹgbẹ awọn apapọ oloṣelu iyẹn League of Registered Political Parties, nipinlẹ Ogun, Ọgbẹni Sunday Ọlapọsi Ọginni, ti ṣapejuwe Sẹnetọ Buruji Kashamu, gẹgẹ bi ẹni ti ko lẹnu nibẹ mọ nidii oṣelu, ti igba ati akoko ẹ ti kọja.
O sọrọ yii lakooko to n ba awọn oniroyin sọrọ, o ni ọkunrin naa kan n fi akoko
ara ẹ sofo ni nitori awọn eeyan ti pada lẹyin ẹ.
Lori wahala to n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ oṣelu PDP ipinlẹ Ogun, Ọginni rọ Kashamu ko
fi ẹgbẹ oṣelu silẹ ni wọrọwọ, ko ma ba a di nnkan ti yoo fi ẹtẹ kuro nibẹ.
Gẹgẹ bo ṣe wi, o ni ẹdun ọkan lo jẹ foun pe Kashamu ko ni itiju rara lori
bo ṣe sọ pe ọkunrin naa ti sọ ara ẹ di ẹni abuku ninu ẹgbẹ oṣelu ipinlẹ naa.
Ọgiini tun sọ pe o ti wa ninu itan pe ko si awọn aṣaaju
oloṣelu ti ọkunrin naa ko tii ba ja, awọn to fi sapẹẹrẹ ni Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjo,
Ọtunba Gbenga Daniel, Ọnarebu Ladi Adebutu atawọn mii in, nitori imọtara ẹni to
n ba ka.
O ni “ Ṣe ẹ ri nnkan to
n sẹlẹ laarin Kashamu ati Oloye Bayọ Dayọ to jẹ alaga ẹgbẹ PDP nipinlẹ Ogun, ti
tubọ tu aṣiri pe ọkunrin ọmọ Ijẹbu-Igbo ko lẹmi imoore
Ọginni wa sọ pe ẹgbẹ
oṣelu lapapọ nipinlẹ gba Kashamu lamọran lati yẹ ara ẹ wo daadaa, ko si pada si
liana ootọ ati eyi to yẹ.
O ni pẹlu gbogbo nnkan to ṣẹlẹ yii, o ti fi han daju pe ko si nnkan fun
Sẹnetọ naa mọ ninu ẹgbẹ PDP, eyi to ni o ti n dari tipẹ.
Ọginni wa lo akoko naa lati rọ awọn to nifẹẹ oṣelu, ti
wọn si tun fẹ iṣejọba lati fọwọsowọpọ fun atunto to n lọ lọwọ ninu ẹgbẹ oṣelu
PDP ipinlẹ Ogun.
No comments:
Post a Comment