Aarin awa ọba pẹlu ijọba ko danmọran lakooko yii- Ọba Iselu, ipinlẹ Ogun - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Monday, 20 April 2020

Aarin awa ọba pẹlu ijọba ko danmọran lakooko yii- Ọba Iselu, ipinlẹ Ogun



Ọkan lara awọn ọba to n ṣe daadaa nilẹ Yewa ni Ọba Akintunde Akinyẹmi, Iselu tiluu Iselu, ọdun kẹẹdogun ree, ti wọn ti wa lori itẹ, ti wọn si n ṣe daadaa niluu naa, laipẹ yii lo ba oniroyin wa sọrọ nipa ilu ẹ atawọn idagbasoke to ti deba ilu na, iṣoro ti wọn koju, bi ifọrọwerọ naa ṣe lọ niyii.

 Orukọ mi ni Ọba Akintunde Akinyẹmi.Iselu tiuu iselu ni Yewa North nipinlẹ Ogun.
Iselu ọmọ Alaketu ni wa. Awa lati Ile-Ifẹ, Bi mo ṣe jọba ni Iselu bẹẹ naa ni mo tun le jọba ni Ketu, nigba ti wọn ja ogun Dahomy, to di orileede Benin lonii, ogun naa mu Alaketu,ọmọ Alaketu ni Aka- Oṣu. Oun lo gbe ade wa si Iselu ta a tẹdo si.

Bawo ni Aka-Oṣi yẹn ṣe jẹ, iru eeyan wo ni?

Ọmọ Alaketu ni,nigba ti ogun yẹn pọ, ninu ẹ ni wọn bi Akasi, Ṣe ẹ mọ aka, ki ogun maja, ki obinrin wa bọ si abẹ aka yẹn, ni ilete oṣu, oun lo jẹ ki a pada wa ti a fi tẹdo si Iselu.

Bawo lẹ ṣe wa tẹdo si Iṣelu?

Oun ni mo fi sọ pe ọmọ Iselu, ẹsẹ ẹ pọ. Ibi ti ẹsẹ ba pọ ti ariwo n ta.Ọmọ Aka-Oṣu, Baba Irawọ.

Nibo gan-an lẹ wa ni Yewa?

Bi ẹ ba ti de ọja-ọdan, ti ẹ bọ silẹ ni ẹ yoo d Iselu

Iyatọ wo lo wa laaarin Ọja-Ọdan ati Iṣelu?

Ko si iyatọ nitori Iṣelu ati  Igbo-ọrọ ọmọ iya ni wọn.Lati iṣelu ni wọn ti tẹ Igbo-ọrọ, Ebute, Ọja-Ọdan.

Ṣe Baalẹ lẹ kọkọ jẹ niluu naa ni tabi ọba?

Awa o ki i jẹ baalẹ ṣugbọn nigba ti wọn ti gbade wọlu la ti n jọba.

Igba wo ni ade ti deluu yii?

Ade ti wa nibẹ lati nnkan bi 18th Century. Nigba to ya ogun wẹẹti ẹ de, to gbona gan-an, iyẹn laye awọn Awolọwọ.Gbogbo igba naa ko si ọba mọ ni Iṣelu. Wọn kan ni asoju.

Nigba to di ọdun 1981, nijọba ipinlẹ Ogun gbe igbimọ kan dide, pe gbogbo awọn to ti n jọba tẹlẹ, ki wọn gbe igbimọ oluwadii, ki wọn le gbe ade, ọpa-aṣẹ wọn atijọ, gbẹdu ọba atijọ, ẹni to ba ti ni ki wọn gbe wa si Ilaro.

Gbogbo awọn ilu bii Iṣelu, Ìjánná,Ìgbéjí, Ìtọ́rọ́,wọn gbe nnkan ade wọn, ọpa aṣẹ ati gbẹdu ọba atijọ, ti wọn n lo tẹlẹ lọ sibi igbimọ naa, lati bẹ ni wọn ti sọ pe awọn to ti ni ade yẹn, ki wọn gba ade wọn pada.

Ọdun wo lẹyin jọba niluu naa?

Mo ti jọba lati ọdun 2005, o ti pe ọdun mẹẹẹdogun sẹyin.

Bawo lẹ ṣe dori ipo yin?

Nigba temi jọba, emi o ki i gbele ṣugbọn baba mi, onimọ-ẹrọ ni.Emi wa niluu oyinbo, nigba to ya ọba to waja,Ọba Fafoye, nigba tiyẹn waja, o ti ku lati ọdun 1991, latigba naa ni wọn ti wa lori awọn yoo jọba, awọn ko jọba.
Baba mi wa ranṣẹ pe mi pe ki n wale, nigba ti mo dele, wọn pe awọn ilu pe awọn ko le jọba, nitori ẹsin igbagbọ ko le fawọn lanfaani, ṣugbọn awọn maa fi ọmọ awọn silẹ lọọ jẹ. Bi wọn ṣe fami silẹ niyẹn pe ki emi lọ jẹ ọba yẹn.

Idile meloo lo n jọba niluu yin?

Ni iṣelu, idile mẹta ni. Ìlésí, Ọgbun ati Ìsabà

Idile wo lẹyin ti wa?.
Ìsabà, a maa n pin ọba laarin wa ni.
Ẹ sọ pe baba lawọn ko le jọba, nitori ẹsin igbagbọ ti wọn gba, wọn gbona gan-an niyẹn o, ẹyin n kọ, ṣe ẹyin o gbona?

Igbagbọ lemi naa, ṣugbọn temi yatọ, mo mọ pe ọba jijẹ wa ninu Bibeli, lati maa paṣẹ, sakoso, igbagbọ temi yatọ si ti wọn, awọn nigbagbọ pe awọn ti sin ijọba fọdun marundinlogoji, awọn si ti wa ninu ẹsin, ọba le din ẹsin awọn lọwọ.

Ijọ wo ni Baba?

Ijọ Kerubu ati Serafu ni. Ẹni ọwọ ni ipo ti wọn di mu.

Ki Ọlọrun to gbeyin depo ọba iṣẹ kin ni ẹ n ṣe?

Mo n ṣiṣẹ niluu oyinbo,  igba mii in ẹwẹ mo n ṣiṣẹ pẹlu ileeṣẹ, ati kilọọbu.

Igba tẹ ẹ wa ni kekere n jẹ ẹ ni lọkan pe ẹ yoo jọba lọjọ iwaju?

Baba mi ko tiẹ sọ fun wa rara pe idile ọba la ti wa, nitori ẹ ni ko jẹ ki n ni lọkan, Nitori ko fẹẹ ki iru nnkan bẹẹ wa lori wa, igbagbọ baba mi ni pe ki onikaluku lọ si ṣooṣi ko si kawe, ati pe ko ko wa lọ sile ri, wọn ko tiẹ ba mi sọ ri. Ibeere akọkọ ti mo si kọkọ beeere lọwọ wọn ni pe ṣe a lẹtọọ si ọba ni.
Wọn sọ pe o dabi ẹni pe ọmọọba ni wa ṣugbọn tawọn ba ti sọ fun wa latilẹ, ko nii jẹ ka kọjumọ nnkan taa n ṣe.Ilana yii lemi naa n tẹle nitori idi eyi ni mi o ṣe jẹ kawọn ọmọ mi fi sọkan. A tiẹ kuku jọ gbe emi wa ni Naijiria awọn wa ni oke-okun.

Laye ọjọun igbagbọ wọn ni pe ifa lo yan ọba, ṣe bẹẹ ni lakooko tiyin?.

Bẹẹni ko to di pe baba mi ni ki n wa jọba ni wọn ti difa, to si mu mi,ifa ilu sọ pe ẹni to maa jọba ko si lorileede yii, ifa idile wa sọ pe emi ni mo maa jẹ, wọn wa ṣẹṣẹ wa lọ ba baba, baba mi wa sọ pe awọn ti gbọ, ṣugbọn awọn ko le jẹ o, ni wọn ṣe wa ranṣẹ pemi.

Bawo lẹ ṣe ri ipo ọba tẹ ẹ wa bayii ati ki ẹ to depo naa?

Nnkan to fi yatọ ni pe awọn ọrẹ mi ti a jọ n ṣe faaji, ọpọ wọn ti sa fun mi, ṣe ẹ mọ ẹlomii in to ba gbọ ọrọ ọba yoo ro pe wọn fi eeyam ṣowo ni, tabi wọn bọrisa ni, awọn min in tiẹ wa sọ debi pe awọn ko le wa dọbalẹ fun ọrẹ awọn.

Lọrọ kan ọrọ ọba ko di faaji mi lọwọ, ti mo ba fẹẹ lọ silu oyinbo maa lọ, ko ni ki n ma jade, o ti yatọ si ti atijọ pe dandan oju kan leeyan maa wa.

Kin ni a le pe ni ooṣa ilu to pa gbogbo ilu pọ?

Ẹlẹgba oro, a maa n ṣe ninu oṣu keje

Bawo lẹ ṣe maa n ṣe e?

Awọn ilu naa lo maa difa, igba to ba ti mu la maa n ṣe.

Ki wa ni ojuṣe ọba lakooko ọdun ooṣa naa?

Ko si ojuṣe kan ju pe mo maa n fun wọn lowo lati ra gbogbo nnkan ti wọn ba fẹẹ ṣe lọ.

Njẹ kin ni awọn nnkan taa le pe ni eewọ ilu?

Eewọ taa ni ko ju pe a ki i jogun, ẹni to ba jogun ma ku ni. Ninu idile kan ki wọn wa sọ pe wọn fẹẹ jogun obinrin, ko jọọ rara, a ki i ṣe bẹẹ.

Bawo wa ni ẹ ṣe maa n ṣe e?

Ti ọkọ obinrin kan ba ti ku, iyawo ẹ a lọ wa ẹlomii in fẹ ni, wọn ko gbọdọ ṣu lopo, koda nnkan ini ọkunrin naa wọn yoo ko fun iyawo ẹ ni, ẹbi ko le jogun ẹ.

Ipo wo ni Iselu wa laaarin awọn ọbalọba ilẹ Yewa?.

Ipo kin-in-ni ni a wa

Ki wa ni ojuṣe yin sawọn eeyan ilu yin?

Ko si nnkan mii i ti mo mọ ni ojuṣe mi ju pe ti ẹnikẹni ba n fẹ iranlọwọ , dandan ni la ti ṣe fun un., ẹni to ba ni iṣoro ka mọ bi a ṣe le ranlọwọ, gbogbo wahala awọn Fulani, ka ke pe ijọba, boya wọn dahun tabi wọn ko dahun, nitori wọn ko jẹ ki wọn gbadun, gbogbo nnkan ti wọn ba fẹ niluu ka sọ fun ijọba. Bo tilẹ jẹ pe a mọ pe aarin wa pẹlu ijọba ko danmọran, a kan ma pariwo naa ni, nnkan ti wọn ba fẹ ṣe wọn a ṣe, eyi ti won ko ba ni ṣe, wọn ko ni ṣe.

Lori wahala to n ṣẹlẹ nipa abadofin kan ti wọn gbe lọ sile igbimọ aṣofin lori igbesẹ bi wọn ṣe jọba, tawọn ọba kan fẹẹ yipada?

A ri ṣe larika, a ri ka n i baba iregun, nnkan ti wọn gbe kiri emi ro pe ko ni itumọ,idi abajọ ni pe ọba ibilẹ iyẹn Traditional ruler la n pe awọn ọba, to ba di a ti n fi ẹsin ṣe, a jẹ pe a ko jẹ orukọ yẹn mọ niyẹn., boya ki a ma lọ sileewe ẹkọ ẹṣin nnkan to tumọ si niyẹn. Igbagbọ ati ẹsin musulumi, wọn ki i ṣe ẹsin ibilẹ.

 


No comments:

Post a Comment

Pages