Lati le jẹ ki gbogbo wahala to n ti waye ninu ẹgbẹ oṣelu PDP lati nnkan bi ọdun meloo wa ṣopin, Onimọ-ẹrọ Bayọ Dayọ to ti figba kan jẹ alaga fẹgbẹ oṣelu naa nipinlẹ Ogun, ti pari gbogbo ija to n waye laaarin Ọnarebu Ọladipupọ Adebutu ati Arẹmọ Adekọya Adeṣẹgun Abdel-Majid tọpọ awọn ololufẹ ẹ mọ si Attacker.
Ọnarebu Adebutu, to ti figba kan jẹ
alaga lori idagbasoke igberiko nile igbimọ aṣoju-ṣofin niluu Abuja loun ati
Ọnarebu Adekoya Adesegun Abdel-Majid, toun ṣi wa nibẹ, nibi to ti jẹ ọlọpaa
ẹgbẹ nile igbimọ ọhun lawọn mejeeji ti fimọ sọkan lati jọ ṣiṣẹ pọ fun ilọsiwaju
ẹgbẹ ọhun, ti wọn si fi gbogbo nnkan to ti n da wahala silẹ laaarin doun
igbagbe.
Ile alaga ẹgbẹ naa tẹlẹ, Bayọ Dayọ,
ni ipade ọhun ti waye lọjọ Iṣẹgun, ọsẹ yii, niluu Ijẹbu-Igbo, ti wọn si tun jọ
jiroro lori ọna ti wọn le gba lati le jẹ ki ẹgbẹ oṣelu naa jawe olubori ninu
ibo ọdun 2023.
Lara awọn to wa nibẹ lọjọ naa ni
Ọnarebu Daisi Akintan, to jẹ akọwe ẹgbẹ naa nilẹ Yoruba, Ọmọọba Sunday Ṣolarin,
akọwe ẹgbẹ ọhun nipinlẹ yii, Kayọde Adebayọ, Agbẹjọro Bọla Kalẹjaiye, Mọgaji
Dele Ajayi, awọn Oloritun lati ilu Ijebu Igbo atawọn mii in.
Bayọ Dayọ wa rọ awọn eeyan ọhun lati
jumọ wa ni iṣọkan lori gbogbo eto ti ẹgbẹ naa ba n dawọle, ki wọn si jẹ ki
ajọṣepọ to danmọran wa laarin wọn, eyi to le mu ẹgbẹ yii goke agba.
Ọnarebu Adebutu, ninu ọrọ bẹ awọn olori ẹgbẹ kọọkan ninu ẹgbẹ
oṣelu naa lati gba isọkan laaye, ki wọn si jọ ṣiṣẹ pọ fun aṣeyọri ẹgbẹ yii, bẹẹ
naa ni Ọnarebu Adekoya naa fi idunnu ẹ han lati ṣiṣẹ pọ pẹlu Adebutu ki wọn le
gba ipinlẹ Ogun lọwọ APC lọdun 2023.
|
No comments:
Post a Comment