Ẹgbẹ oṣelu APC ati PDP fatilẹyin wọn han si Ọgiini alaga IPAC nipinlẹ Ogun. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday 7 August 2020

Ẹgbẹ oṣelu APC ati PDP fatilẹyin wọn han si Ọgiini alaga IPAC nipinlẹ Ogun.

 


 Ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress iyẹn APC ati Peoples Democratic Party, PDP, nipinlẹ Ogun, lawọn ti ṣetan lati ṣiṣẹ pọ pẹlu alaga tuntun fawọn apapọ ẹgbẹ oṣelu, Inter Party Advisory Council, IPAC, iyẹn Ọgbẹni Sunday Ọlapọsi Ọginni, lati le mi aṣeyọri baa lakooko ẹ.


Awọn ẹgbẹ oṣelu mejeeji  ṣeleri yii lakooko ti wọn n ba oniroyin sọrọ lẹyin ti wọn pari ipade wọn to waye ni Adatan, niluu Abẹokuta.

Wọn sọ pe ọrọ ẹnu kọ, Ọginni ni ojulowo alaga ẹgbẹ naa tawọn mọ, ti wọn si ṣe itẹwọgba ẹ, wọn ni ẹnikẹni to ba pe ara ẹ ni alaga lẹyin ọkunrin naa ayederu ni, nitori wọn ko lẹnu nibẹ.


Clement Adeniyi,  to jẹ olori awọn ọdọ ninu ẹgbẹ oṣelu APC, ṣalaye pe oun wa pẹlu aṣẹ alaga ẹgbẹ ọhun nipinlẹ Ogun, Yẹmi Sanusi lati wa ṣoju wọn fun ti ẹgbẹ yii ninu IPAC. 

O fikun ọrọ ẹ pe Oginni ni alaga ẹgbẹ apapọ ẹgbẹ oṣelu ti APC tẹwọgba nipinlẹ Ogun .  O ni awọn ṣetan lati ṣiṣẹ pọ pẹlu ẹ lati fọwọsowọpọ pẹlu ijọba to wa lode yii, ki mudunmudun ijọba le tẹ gbogbo awọn lọwọ

Ninu ọrọ ti Deji Ashaye, to jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP, to ni oun wa ṣoju awọn igun mejeeji ninu ẹgbẹ naa sọ ni tiẹ pe ko si alaga IPAC tawọn tẹwọgba, bi ko ṣe eyi ti Ọginni jẹ adari wọn.

Ko to to akoko yii ni Ọginni ti ṣeleri pe ko ni si ojuṣaaju kankan ninu ijọba oun, o ni oun kan jẹ alaga IPAC ni, ṣugbọn gbogbo wọn lo jẹ alaga lawọn ẹgbẹ oṣelu kọọkan ti wọn ti wa, o wa bẹbẹ fun isọkan ati ifọwọsowọpọ, ki wọn le jọ ṣaseyọri, nitori iṣẹ pọ tawọn yoo ṣe.

 

Lara awọn to wun wa nibẹ lọjọ naa ni awọn aṣoju lati inu ẹgbẹ oṣelu Allied Peoples Movement,APM, Accord, BOOT, African Democratic Party, Social Democratic Party,SDP ati NRM.

 

No comments:

Post a Comment

Pages