Bo tilẹ jẹ pe ijọba ipinlẹ Ogun sọ ni ibẹrẹ ọsẹ yii pe ounjẹ tawọn n pin fawọn eeyan lakooko ti wọn n gbele fun ti arun korona fairọs ki i ṣe fun ẹlẹgbẹjẹgbẹ tabi idagbasoke bi ko ṣe awọn to ku diẹ kaato lawujọ, ṣugbọn ni bayii, wọn lounjẹ naa ti di isọnu nitori awọn ti wọn sọ pe awọn ni lọkan lati fun ko de ọpọ ọdọ wọn.
Gẹgẹ bi a nnkan taa gbọ nnkan tawọn ẹlẹgbẹ idagbasoke ti
wọn sọ fun pe awọn yoo maa ko ounjẹ naa fun sọ ni pe wọn kan fi n sọ awọn lẹnu
ni, nitori awọn ounjẹ ti wọn ko fawọn ko nnkan tawọn le fawọn to ku diẹ kaato
gan-an ko to nnkan.
Awọn to ba oniroyin wa sọrọ sọ pe awọn aworan ati ariwo
ti wọn pa lori tẹlifiṣan ati redio lori bi wọn ṣe n pin ounjẹ naa, arumọjẹ ni
nitori nnkan ti wọn pin fawọn eeyan ko ṣe fẹnusọ.
Ọpọ awọn olori idagbasoke lawọn eeyan wọn ko nigbagbọ
ninu wọn, ti wọn sọ pe wọn ko ounjẹ naa pamọ, wọn ko fẹẹ fawọn. Fun apẹẹrẹ ni
Agbado, ohun ti wọn ko fawọn eeyan naa lati pin ko ṣe fẹnu sọ, titi di akoko
taa si n sọrọ yii, awọn kan ko tii gba.
Iroyin kan ta a tun gbọ ṣugbọn ti a ko ti i fidi ẹ mulẹ
ni pe wọn ni wọn ti kọwọ oṣelu bọ nnkan ti wọn pin, wọn lawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu
APC ti wọn wa lawọn wọọdu, ni wọn lanfaani sawọn ounjẹ tijọba ipinlẹ naa pin
lakooko korona fairọs yii, wọn ni wọn fi n gbẹsan lara awọn ti wọn ki i sọmọ ẹgbẹ
wọn.
Ju gbogbo ẹ lọ, awọn araalu ti sọ pe isọnu gba a ni ounjẹ
ti wọn pin, ti wọn ko si fi ibẹru Ọlọrun si i.
No comments:
Post a Comment