Ọpọ aṣeyọri ni mo ti mu ba ilu Odo- Naforija- Aladesọnyin tilu Naforija Ẹpẹ - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday 9 April 2020

Ọpọ aṣeyọri ni mo ti mu ba ilu Odo- Naforija- Aladesọnyin tilu Naforija Ẹpẹ
Ọdun kẹtadinlogun ree ti Ọba Babatunde Ogunlaja, Aladesọnyin tilu Odo-Naforija ni Ẹpẹ, ti jọba. Ọpọ awọn eeyan ni ko mọ pe ọkan lara iran Awujalẹ Ijẹbu lawọn araalu ilu naa nitori abẹ ipinlẹ Eko ti wọn pin wọn si. 
Ọba naa gba oniroyin wa lalejo si afin ẹ, nibi to ti ba wa sọ, biluu naa ṣe tẹdo, ajọṣepọ to wa laaarin wọn ati Ijẹbu pẹlu awọn ọba alaye yooku. Ohun to ba wa sọ niyi.

Njẹ ẹ le sọ nipa ilu Odo-Naforija

Mo le sọ diẹ nipa bi ilu Naforija ṣe tẹdo.O jẹ ọkan lara ilu to ti wa tipẹtipẹ,lati nnkan  bi 19 centur
O jẹ ọkan lara iran Awujalẹ ti Ijẹbu.Bi ilu naa ṣe ṣẹ, laye atijọ ti awọn ọmọọba ba fẹ gbominira lọ tẹdo, wọn a gba iyọnda lọwọ baba wọn, yoo fun wọn ni agbara.

Ẹlomii-in ninu wọn le jẹ ọdẹ, ki ẹlomii-in jẹ oloriṣa. Baba wọn a fun wọn ni iyọnda ati ogún ti wọn.Wọn a wa bẹrẹ irinajo wọn, laye atijọ, irinajo awọn to tẹdo si ileto si ileto.

Ifa lo maa n dari wọn bi wọn ṣe maa tẹdo, ti wọn ba ti gbera lati ibi ti wọn ti ṣẹ,eyi to ba jẹ ọmọọba awọn ami ti wọn fi le da mọ pe ọmọọba ni baba wọn a ko le wọn lọwọ.To ba jẹ oloriṣa, wọn a fun wọn ni nnkan oosa lati mu dani lọ sibi ti wọn ba tẹdo si.

 Aladesọnyin jẹ akọni ẹda kan, nigba to  fẹẹ gbera lati ọdọ baba, wọn ko ohun elo ti ọmọọba fun un. Bo ṣe gbera to n bọ, ibi to duro si ti wọn n pe ni odo Naforija loni in, ifa lo tọ ọ sọna.

Odo Naforija ti ẹ n gbọ yẹn ibi tawọn ọba fi ṣe ipẹbi, ti wọn ti podo sii, o wa jẹ odo ti ọna fori sọ tabi fori ja si. Yoruba maa n sọ pe odo yẹn o, ọna fori sọ ni o,tabi ọna fori ja si ibi kan ni, ni wọn ṣe n pe ni Naforija.

Adesọnyin lẹni akọkọ to tẹ ibẹ do,lẹyin to lọ tan, tawọn ọmọ ẹ wa gbakoso ni wọn sọ ọ ni Aladesọyin. Ede ilu lo ti gba gbogbo nnkan, fun apẹẹrẹ, bi ẹ ba gbọ ti wọn sọ pe ẹyin idi, awọn kan maa n sọ pe ẹyin odi ilu ni wọn n pe bẹẹ, irọ si ni, nnkan ti wọn pe bẹẹ laye ọjọun  ni pe ẹyin ko ti i di, itumọ ẹ ni pe ọmọ ṣi wa ninu ti wọn fẹ bi, ti wọn ba sọ pe ọmọọba kan, ẹyin-idi, ohun to tumọ si ni pe wọn pẹ ki wọn to bi i.

Nigba ti wọn yoo bi ọmọ Aladesọnyin, ẹni to bi gbẹyin ni wọn pe ni ẹyin-idi. Wọn ko mọ pe wọn tun le bimọ mọ. Ṣe ẹ wa ri  ori apeere temi wa yii, Oligbe ni orukọ babanla temi, awa si ni akọbi Aladesọnyin.

Ọmọ mẹta ni Adesọnyin bi, Oligbe ni akọbi, Ajana tẹle, Ẹyindi ni kẹta,ni bayii gbogbo nnkan ti yi pada ko si yẹ ko yipada,ohun lo jẹ ki ẹru wa fawọn ti ko ba si ni ti Ọba.

A o gbọdọ gba ki asa ati iṣe wa ko parun, onikaluku lo ni aye tiẹ. Iru ilu ta a wa yii oriṣiriṣi ooṣa lo wa.

Iran Awujalẹ lẹ sọ pe ẹ ẹ ti wa, bawo lẹ ṣe wa wa labẹ ijọba ibilẹ Eko?.

Eto isakoso lo jẹ ko ri bẹ, ṣe ẹ mọ mo sọ lẹẹkan pe gbogbo nnkan lo ti yipada.Ibi bayii nibi ti awọn oyinbo ti maa n gba awọn ẹru, nigba ti awọn oyinbo Portugal ni wọn kọkọ ṣe owo ẹru nilẹ Naijiria,gbogbo igba naa ko si mọto, ko si nnkankan, ẹsẹ ni wọn fi maa n rin lati ṣe gbogbo nnkan ti wọn ba fẹ ṣe.

Ilu kan wa ta a n pe ni ilẹ- omi,nibẹ ni wọn ti n ko awọn ẹru yẹn bọ, iyẹn lo jẹ ka mọ pe Naforija ti wa tipẹ  ninu iwe itan tawọn Portugal kọ. Nigba ti ilu yii fi wa abule to wa ni agbegbe ẹpẹ yii boya lo to marun-un.

Awọn oyinbo yii mu ẹnikan ti wọn pe ni Ọṣibẹkunde, O jẹ ẹnikan to laju ninu wọn, wọn wa muu mọra, nitori gbogbo bi wọn ṣe n rin, oun lo tọ wọn sọna.

Nibi to le de nigba ti wọn n lọ, wọn ko fi silẹ, bi ẹ ba de Portugal, ni France, orukọ iran wọn si wa nibẹ di ọla.Wọn ko ṣẹru mọ nibẹ, wọn ti wa gbooro bayii nibẹ.

Ọṣibẹkun yii lawọn oyinbo yii maa n lo lori nnkan ti wọn ba n ṣe, bi onikalulu ṣe n gbominira yẹn ni wọn ọ sọ lorukọ to ba wu wọn. Igba ta a kuro labẹ ijọba oyinbo amunisin.

Wọn da ijọba Eko silẹ, nigba ti wọn wa n pin awọn ẹnu bode ilu,labẹ isakoso, abẹ Eko ni Ẹpẹ bọ si nigba naa. Iyẹn ko sọ pe ki iran wa parẹ, ki a ma le tọpaṣẹ ibi ta a ti wa.

Ko si bawọn kan ṣe le pin wa, orisun wa gbọdọ wa nibẹ, idi niyii taa fi dero ipinlẹ Eko niyẹn.

Njẹ ajọṣepọ wa laaarin ẹyin atawọn Awujalẹ ati Ijẹbu lapaapọ?

Titi di ọla ni ajọṣepọ fi wa,Awujalẹ mọ wi pe ọmọ oun lawa.Ni Eko, ọba Eko gan-an maa n sọ, nigba ti wahala kan sẹlẹ iyẹn ti Kosọkọ,Ọba Akinolu sọ fawọn iran Kosọkọ to ku pe Ẹpẹ ilẹ Ijẹbu ni o.

Iya Kosọkọ paapaa iya ẹ tun wa tan si Ijẹbu. Wọn ajoṣepọ abẹlẹ, ẹnikan ko le ba ẹnikan ja. Nigba ti ija yẹn fẹẹ le ni Ẹpẹ, Awujalẹ ranṣẹ wa pe Kosọkọ ki i sẹni ti ẹ le ba ja o, ọmọ iya yin ni o.Ọja ipọnmọ lo fi paroko. Aroko yẹn tumọ si pe ija ti ẹ n ja, ẹ jawọ, ẹbi ni yin.

Idile meloo lo wa n jọba niluu yin?

Idile mẹta lo yẹ ko maa jọba ṣugbọn mẹrin ni. Ki alaafia le jọba lo ṣe jẹ bẹ, awọn idile mẹta to n jọba Oligbe ni akọbi, Ajana ni aburo, Ẹyindi ti mo sọ lẹẹkan ni abigbẹyin.

Nnkankan ṣẹlẹ nigba kan, lara awọn ọmọ ti Ajana bi yii,wọn bẹrẹ ijangbọn pẹlu baba wọn, ija ojoojumọ. Nigba yẹn Oligbe to jẹ akọbi oun lo n sakoso  nigba ti baba wọn ti lọ,wọn bọwọ fun ara wọn, ki i ṣe aye ode oni-in, to jẹ pe abigbẹyin ni yoo maa paṣẹ.

Nigba naa lọhun, gbogbo ogún ti baba wọn ba ni, ko ba jẹ obinrin lakọbi tabi ọkunrin, oun lo maa sakoso ẹ. Ko si ni ṣoju ṣaaju.

Awọn ọmọ Ajana mẹta ni wọn, Bi wọn ba ti n ja pẹlu baba wọn, wọn yoo ti wa ke ba Oligbe to jẹ ẹgbọn pe awọn ọmọ aburo yin tun ti bẹrẹ ija o.
Oligbe a lọ bawọn, igba ti wahala wa pọ lati ko wọn kuro labẹ baba wọn,Deṣẹku, Oṣibuwa o wa ko wọn lọ sibi ti wọn n pe ni Itun ọmọ.

Nigba ti wọn wa fẹẹ pin idile to maa jọba,tẹlẹtẹlẹ bi ọba ṣe bi wọn, ni wọn n tẹle ara wọn, nigba ti ọlaju de, ko ma ba si ede aiyede nijọba wa sọ fun wọn pe, ẹ ni lati sọ bi ẹ ṣe maa pin kinni yii o.

Awa mẹtẹẹta wa pin laaarin ara wa, ni bayii, awọn ọmọ eyi taa lọ ko, bawo la ṣe fẹẹ ṣe wọn, ṣe a maa ko wọn mọ baba wọn Ajana ni tabi ki wọn duro sibi ti wọn wa, ti wọn ba fẹẹ duro sibi ti wọn wa, a gbọdọ fun wọn ni ominira ni.

Ominira ti wọn fẹẹ gba yẹn, a gbọdọ pin nnkan ta a ba n ṣe. Iyẹn ni wọn ṣe ni ka fawọn Itun ọmọ yẹn naa ni ominira, tawọn mẹtẹẹta to ba jẹ ojulowo ọmọ ba ti jọba tan, ki wọn maa fawọn naa.

Ṣe lara wọn wa ti jọba ri?

Ẹn oore-ọfẹ yẹn maa wa fun wọn bayii.Ohun temi maa n ṣe ni pe nnkan ti wọn ba fun wa, mẹrin la maa n pin si.

Kin ni awọn ooṣa ilu yin?

Ooṣa ta a ni niluu yii, gẹgẹ bi mo ṣe sọ pe nigba tawọn baba yẹn n bọ ni wọn ti ko ooṣa wọn fun wọn, lara ẹ ni oro, gbogbo wa la mọ pe gbogbo Ijẹbu lo ni oro. Ko siluu ti wọn maa de, nigba yẹn, o niṣẹ ti oro yẹn maa n ṣe fun wọn. Tọsan-toru ni wọn maa n rin.

Ki oro to wa ke, o lawọn nnkankan ti wọn gbọdọ ṣe, boya a ni ki wọn bọgun,ko sẹni ti ko mọ pe ogun, ọbatala wa, ooṣa nla wa, ko si ooṣa ti wọn n bọ ni Akilẹ- Ijẹbu, ti ko si nibi.

A maa n ṣọdun ẹ̀bí, ta a ba fẹẹ ṣe gbogbo awọn ooṣa yẹn, la maa n tọju. Ninu oṣu kẹrin la maa n ṣe e. Nitori awọn ọmọ to wa lokeere gbọdọ wale, lati wa gbadura. A si ti bẹrẹ imurasilẹ ẹ.

Ọdun keloo ree tẹ ẹ ti wa lori oye?

Lagbara Ọlorun, o ti n lọ bi ọdun mẹtadinlogun bayii.

Ko to di pe ẹ dori oye, iṣẹ wo lẹ n ṣe?

Mo ti n ṣiṣẹ lọna to pọ. Mo mọ nipa ohun elo ina, iyẹn nikan kọ, mo ti ṣiṣẹ pẹlu Oloye MKO Abiọla. Nigba to ya mo pinnu lati da iṣẹ temi silẹ.Mo maa n rin irinajo lọ si oke-okun lati lọ ra ọja, ti mo maa pada  wa sile.

Njẹ ẹ ni lọkan ni kekere pe ẹ yoo jọba lọjọ iwaju?

Ṣe emi tiẹ mọ pe wọn n jọba niran mi, ti mo fi maa ni lọkan pe mo fẹẹ jọba, ṣe ẹ ri gbogbo nnkan wọnyii laye atijọ, ẹni to ba fẹẹ jọba kọ lo maa sọ lọkan ẹ pe oun fẹẹ jọba.Ni wọn fi maa n sọ pe ọlọgbọn kan ko fira ẹ jọba, ọmọran kan ko fira ẹ joye. Eeyan kọ lo ma sọ bẹẹ, awọn kan ni wọn yoo wadii pe idile wo lo kan, gbogbo igba ti Ọba Benjamin Ayantuga, to gbesẹ, to lọ, emi ko ni lọkan pe wọn jọba nile temi. Awa ki i toju sibẹ, ko dabi ode iwoyii, to jẹ pe ateyi to kan wọn, ati eyi ti ko kan wọn ni wọn maa koju bọ.

Bawo wa ni wọn ṣe mu yin?

Nigba tọba ti waja ni wọn ti n wa ẹni ti yoo kan, awọn ọmọ wo lo wa ni idile yẹn, to ba jẹ marun-un, wọn a ko wọn jọ. Wọn a wa lọ fi ifa yẹ ẹ wo,ifa ni yoo sọ pe lagbaja bayii lo tọ si. Ibikibi  tonitọhun ba wa, wọn yoo wa kan.

Ọjọ akọkọ ti wọn lẹyin ni ọba, bawo lo ṣe ri lọkan yin?
Lọkan mi, mi o ro, nitori nnkan ti mo n ro ni pe ti wahala ba ti wa, emi maa n fẹ ka pari ẹ.Ọkan ninu awọn ọdọ yẹn lo sọ fun mi pe o dabi ẹni pe idile yin lo kan. Ija ni mo gbe ko wọn loju pe nigba to kan idile mi n kọ, kinni wahala wọn.

Mo sa lọ, pada sẹnu iṣẹ mi. Bi mo ṣe tun maa pada wa, nitori oju mi ko gba pe ki wahala maa ṣẹlẹ.Nigba to si jẹ pe olori ẹbi idile wa ni baba mi jẹ.

 Awọn baba kan wa ki Ọlọrun fọrunkẹ wọn, ẹnikan sọ pe oun fẹẹ ba wa du, ni wọn ba sọ pe mi o gbọdọ gba o, pe ẹniyẹn ko ni ipin ninu ẹ o, awa gan-an lo tọ si. Baba mi o tiẹ gba, nitori emi nikan lọkunrin to bi.

Nigba to fẹ wa maa debi iwọsi ni mo sọ pe nnkan ti wọn tori ẹ ja yii, ṣe baba yii ko ni ipin si ni. Laimọ pe ẹni to loun fẹ jọba ko ni ipin si rara. Wọn bẹrẹ si ni pa itan fun un pe kinni yii, ko kan-an,idile ẹni to kan niyẹn.

A ṣe wọn ti mu pepa ti wọn sọ pe orukọ to wa ninu pepa ti wọn mu da ni ni ifa mu, ṣugbọn ẹni ti pepa naa wa lọwọ ẹ ko fẹẹ fi silẹ,o ki bọnu agbada bawọn ọdọ ṣe yari niyẹn pe a fi ki wọn jẹ ki wọn wo orukọ yẹn bo ṣe di orukọ mi niyẹn.Ọdun mẹsan-an la fi rin irinajo naa, ki awọn alaalẹ to fọwọ si, ti Ọlorun ṣi lo Asiwaju Ahmed Tinubu.

Kin ni awọn aṣeyọri yin?

Aṣeyọri to pọ lo ti ṣẹlẹ lakooko ti mo ti jọba niluu yii.

Njẹ eewọ wa niluu yii?

Gbogbo eeyan lo ti mọ pe obinrin ki i foju kan oro,kinni kan wa ṣẹlẹ lakooko ta a n ṣe oro ti ọdọ wa, wọn ni nnkan ta a ba fẹẹ ṣe, a o gbọdọ gba alejo laye, alejo to jẹ birikila to loun fẹẹ lọ ṣiṣẹ nibẹ, ṣe lo bẹrẹ aisan, bo ṣe kuro nibẹ niyẹn.

Aarẹ ẹgbẹ Heritage ti wọn fi yin ṣe, ki lo nii ṣe pẹlu awọn ọba alaye nilẹ Yoruba?

Nnkan ti mo le sọ nipa ẹ pọ, nigba ti wọn kọkọ wa sibi, mo sọ fun wọn pe emi o ki i ṣẹgbẹ o, bi ẹ ba ni nnkan ṣe, mo le ran yin lọwọ o. Bi wọn ba fẹẹ ṣe nnkan, a n ran wọn lọwọ,mo wa bẹrẹ si nii foju wolẹ, mo ri pe ohun ti wọn n ṣe da lori awa ọba ilẹ Yoruba.

Ẹni to ba n ṣe iru nnkan bẹẹ ọrẹ mi ni.Nitori mo mọ pe a ni lati gbe asa wa ga.Ọjọ kan nigba ta a lọ ba Ọba Oni-gbehin ṣe nnkan, a ṣe wọn ti gbe igbese pe emi ni mo maa jẹ aarẹ gbogbogboo ẹgbẹ naa, ko si nnkan ti mo le ṣe nibi ti wọn ti sọ yẹn, bi mo ṣe gbe agbelebu ẹ ni. Mo si dupẹ lọwọ Ọlọrun pe a ṣe awọn aṣeyọri.

A ti ṣe apejọ awa ọba lọdọ Ọọni, a n mura lati lọ si Ọyọ, ni Akẹsan jona ta a le lọ.  A si ti n pinnu lati ṣe tọdun yii, Ọọni si ti n mura silẹ lati gba wa lalejo.

1 comment:

  1. Meanwhile, BK8 also presents an intensive number of live dealer blackjack options, together with American, VIP and Lightning variants. Their site is straightforward to use on desktop and cell, while customer support is out there 24/7. Overall, it is clear to see why BK8 has turn into such a well-liked gambling platform over current years. There is now converging proof that suggests social casino players migrate to online gambling (Gainsbury et al. 2016; Kim et al. 2015). Social casino 우리카지노 video games are also in style amongst adolescents and younger adults.

    ReplyDelete

Pages